Unknown gunmen attack: Àwọn agbébọn kọlu àgọ́ ọlọ́pàá ní Anambra, wọ́n tún pa ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan ní Enugu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn afurasi agbebọn kan ti yibọn pa ọlọpaa mẹrin nilu Obeagu, nijọba ibilẹ Enugu South lọjọ Satide.
Ninu fidio kan to n lọ kaakiri ayelujara ni iṣẹlẹ naa ti fọn si igboro aye.
Iroyin to n kaakiri n sọ pe nnkan bii agogo mẹta ọsan ni ikọlu to ja si iku fun awọn ọlọpaa naa waye.
Iku awọn ọlọpaa yii n waye lẹyin ọjọ kan ti awọn agbebọn kọlu ibudo igbafẹ Meniru street park ni Gariki nipinlẹ Enugu.
- Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní Abeokuta
- Ìdí tí mo fi ní ọ́jọ́ ikú ni ọ̀la ọjọ́ 'Valentine' fún àwọn kan- Mike Bamiloye
- Olubadan tuntun yóò di mímọ̀ lọ́jọ́ Ajé - Gómìnà Makinde
- Tí o bá ń pẹ́ jẹun alẹ́, o lè ní àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti asétọ̀
- Àwọn jàndùkú agbébọn tún kọlu ilé Sunday Igboho, èèyàn kan dèrò ọ̀run
Ni Ọjọbọ lawọn agbebọn yinbọn pa oluṣọ abo kan ti orukọ rẹ n jẹ Jango.
Ninu fidio naa to n lọ kaakiri, ohun ariwo awọn ero inu ọkọ kan to n kọja ni ibudo ayẹwo awọn ọlọpaa nibi ti wọn ti ṣe afihan oku eeyan kan to wa ninu aṣọ ọlọpaa pẹlu ẹjẹ lara rẹ.
Awọn to wa lagbegbe naa ṣalaye pe ọkọ Sienna ati Lexus Jeep kan ni awọn agbebọn to kọlu awọn ọlọpaa naa wa lasiko ti wọn fi fẹ kọja nibudo ayẹwo awọn ọlọpaa naa.
Ni ọjọ meji si ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ni awọn agbebọn kan ti kọlu ibudo ayẹwo awọn ọlpaa kan lagbegbe Timber Shade nilu Enugu ti wọn si pa eeyan mẹrin nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo lọrọ ṣe ri nipinlẹ Anambra?
Iroyin lati ilu Uli lagbegbe Ihiala nipinlẹ Anambra pẹlu ko fararọ pẹlu bi awọn agbebọn kan tun ṣe kọlu agọ ọlọpaa kan nibẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọ̀lọpaa ni ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣugbọn o ni ko si ọlọpaa to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Agbegbe Ihiala jẹ agbegbe kan ti wahala ati ifigagbaga laarin awọn agbebọn atawọn agbofinro ti n waye.
Koda jọ diẹ sẹyin lawọn ologun yinbọn pa awọn agbebọn mẹrin kan ninu aṣọ dudu nigba ti wn gbena woju awọn ologun naa.
Ọmọogun kan naa ku sinu iṣẹlẹ naa.
Eto aabo nbajẹ ni ipinlẹ Anambra
Oniruuru ikọlu awọn agbebọn lo n waye agbegbe Ekwulobia ati Ihiala nipinlẹ Anambra lẹnu lọwọlọwọ yii ti awọn agbofinro si n gbiyanju lati wa ọwọ wọn wa silẹ.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, lasiko eto idibo sipo gomina nipinlẹ Anambra lọdun 2021, idibo ko waye lagbegbe ijọba ibilẹ Ihiala lọj ti wọn kọkọ mu fun idibo nitoru ibẹrubojo lori ọrọ abo.
Wọn sun idibo nibẹ si ọsẹ keji to tẹle e.
Eto abo mẹhẹ pupọ lẹkun ila oorun orilẹede Naijiria pupọ lọdun 2021.
Lara awọn ohun to n tigi bọ oju eto abo lẹkun naa ni ijinigbepawo, ikọlu awọn agọ ọlọpaa, ajọ eleto idibo, igbenipa, iklu awọn ọgba ẹwọn atawọn ileeṣẹ gbogbo to jẹ tijọba.


















