Olubadan throne: Gómìnà Seyi Makinde ní ìgbìmọ̀ olóyè Ibadan ti fún òun lórúkọ Olubadan tuntun, ìkéde yóò wáyé lọ́jọ́ Ajé

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Gomina ipinlẹ Ọyọ ti kede pe lọjọ Aje loun yoo kede Olubadan tuntun ti ilẹ Ibadan.
Ni ọjọ Satide ni gomina Ṣeyi Makinde sọrọ naa nibi eto igbalejo ayẹyẹ ogoji ọjọ isinku Olubadan to waja, Ọba Saliu Akanmu Adetunji.
Lara awọn eekan ilu Ibadan to wa nibi eto naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Ọjọ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan, gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Rashidi Ladọja pẹlu Sẹnetọ Kola Balogun to n ṣoju ẹkun idibo guusu ipinlẹ Ọyọ nile aṣofin agba.
- Àwọn jàndùkú agbébọn tún kọlu ilé Sunday Igboho, èèyàn kan dèrò ọ̀run
- Ilé alájà mẹ́ta dàwó ní Yaba nílùú Eko, àwọn èèyàn há sábẹ́ rẹ̀
- Mubarak, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ibadan lọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ikú rẹ̀ - àwọn ọ̀rẹ́ kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- Ipò Ààrẹ gbọdọ̀ padà sí ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún 2023 - Afenifere
Kini Gomina Makinde tun sọ?
Gomina Makinde ni ọna ti la fun oun lati ṣe ikede Olubadan tuntun naa bayii lẹyin ti oun ti tẹwọ gba lẹta latọdọ igbimọ afọbajẹ ilẹ Ibadan lori ẹni ti ewe oye bọ le lori.
Gomina Makinde ṣalaye pe ọtọ laye ilu Ibadan, paapaa ti a ba n sọrọ oye jijẹ.
"Ibadan ko dabi awọn ilu miran nibi ti o ti n gba wọn to bii ọdun meje ki wọn to ri ọba jẹ lẹyin ti ọba kan ba gbesẹ."

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde/ facebook
Saliu Akanmu Adetunji, ti a bi ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 1928, waja ni ọjọ keji oṣu kini ọdun 2022.
Ẹni ọdun mẹtalelaadọrun ni nigba to ju awa silẹ nileewosan nla UCH.
Oun si ni olubadan kọkanlelogoji to jẹ.
Ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2016 ni Ọba Adetunji gun apere Olubadan ti ilẹ Ibadan.
Ki lawọn ohun to ti ṣẹlẹ lẹyin iku Ọba Saliu Adetunji?
Gbogbo eeyan lo n reti ki wọn kede ẹni to kan lori ila oye jijẹ ni igbimọ agba oye ilẹ Ibadan gẹgẹ bii Olubadan tuntun bi wọn ṣe maa n sọ pe 'mọkanmọkan loye Ibadan.'
Amọṣa ọrọ ko ri bi ọpọ ṣe ro o nitori pe awuyewuye pe Oloye Lekan Balogun ti oye naa kan ko ni le e jẹ lo gbode.
Bawo ni ọrọ ipẹjọ Amofin Michael Lana ṣe bẹrẹ?
Eyi ko ṣẹyin bi amofin kan, Michael Lana, to jẹ ọmọbibi ilẹ Ibadan ṣe kọwe ifisun si gomina ipinlẹ Ọyọ.
O ni pe Lekan Balogun ko lee de ade meji lẹyin to ti gba lati de ade lasiko ti gomina ana, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ti s awọn oloye ibadan, awọn Mgaji atawọn Baalẹ kan di ọba to n de ade.
Amofin Lana ṣalaye pe ko si ninu iwe ofin oye jijẹ ilẹ Ibadan pe ọ̀ba alade le jẹ Olubadan, "Oloye lo n jẹ olubadan'
Amofin Lana to ti figba kan ri jẹ amofin agba ati kọmiṣọnna feto idajọ ni ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe oloye Kọla Balogun atawọn agbaoye kan nigbimọ olubadab ti gba ade gẹgẹ bi ọbalasiko iṣejọba Gomina Abila Ajimọbi
Eyi fa ọpọ awuyewuye ati ikayasoke lori ibi ti kangunkangun-kangun ọrọ naa yoo kangun si.

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde/ facebook
Bawo ni ilana ofin jijẹ Olubadan ṣe yẹ ko waye?
Ni ibamu pẹlu ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan, asiko Oloye Lekan Balogun to jẹ Ọtun Olubadan lo kan lati jẹ ọba.
Amọṣa ekuru fẹ gbẹyin ni ifanfa fun un pẹlu bi oun atawọn agbaoye miran kan ṣe gba ki gomina ana sọ wọn di ọba alade eyi ti ọpọ alẹnulọrọ ati onwoye n sọ pe o tako ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan.
Oloye Lekan Balogun pẹlu awọn agba oye bii Oloye Owolabi Ọlakulẹhin, Balogun ilẹ Ibadan; Tajudeen Ajibọla, Ọtun Balogun ilẹ Ibadan; Oloye Eddy Adewọle, Aṣipa Olubadan; Oloye Abiọdun Kọla Daisi, Ẹẹkẹrin Olubadan ati Hamidu Ajibade, Ẹkarun un Olubadan ṣe faake kọri lati tako aṣẹ Olubadan to waja pe wọn ko gbọdọ tẹle ohun ti gomina ana fẹ fi wọn ṣe.
Ijiroro to waye laarin awọn eekan ọmọ bibi ilẹ Ibadan, awọn ololufẹ ilẹ Ibadan ati gomina pẹlu awọn oloye igbimọ olubadan ni wọn ti fẹnuko pe ki awọn agba oye naa o lọ pada si oye ti wọn wa tẹlẹ ki wọn si l gbe ade ti sẹgbẹ kan.
Bakan naa ni wọn tun fẹnu ko pe ki gbogbo awọn to gbe ẹjọ l si ile ẹjọ lọ wọgile ẹjọ bẹẹ ki wọn to lee mọ igbesẹ to kan.
Gbogbo eleyii ni awọn ti ọrọ kan ti ṣe ni ṣiṣẹ n tẹle.
Bi ọrọ ṣe ri bayii, ko tii si ẹni mọ boya Agba oye Lekan Balogun ni tabi oun kọ; o di igba ti gomina Makinde ba kede eyi ljọ Aje ki ẹnikẹni to lee mọ ẹni ti yoo jẹ Olubadan tuntun.



















