Àwọn jàndùkú agbébọn tún kọlu ilé Sunday Igboho, èèyàn kan dèrò ọ̀run

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe eeyan kan dero ọrun nigba tawọn janduku agbebọn kan ṣe ikọlu sile Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lọjọ Abamẹta niluu Ibadan.

Agbẹjọro Igboho, Yomi Aliu(SAN) lo fidi ọrọ yii mulẹ fun iwe iroyin Punch.

Aliu ṣalaye pe awọn janduku ọhun doju ija kọ awọn ọmọlẹyin ajijagbara ilẹ Yoruba un ni pẹlu oriṣiiriṣii ija oloro bi ada.

Aliu ni ile kan naa tawọn ọlọpaa DSS kọlu lọjọ kinni oṣu keje ọdun 2021 lagbegbe Soka niluu Ibadan lawọn janduku yii tun kọlu.

O fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ọmọlẹyin Igbvoho ti wọn ba nile lo farapa nigba ti ẹnikan ninu wọn gbẹmi mi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ko gbe ago wọn lati sọrọ lori iṣẹlẹ yii nigba tawọn akọroyin kan si wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ni ọhanjọ oru lawọn ajọ DSS kọlu ile Igboho lọdun 2021.

Koda eeyan meji ni wọn ṣekupa lọjọ naa lọhun nigba ti wọn ko mejila ninu awọn ọmọlẹyin rẹ lọ si ahamọ niluu Abuja.

Wọn pada fawọn eeyan naa lominira lẹyin ti wọn ti wa latimọle fun oṣu diẹ.

Lẹyin ikọlu yii ni ajọ DSS sọ pe awọn n wa Igboho nitori ọdaran nii ṣe.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ko nkan ija oloro sile lati da Naijiria ru, eleyii ti Igboho ni irọ nla ni ọrọ naa.

Igboho fi Naijiria silẹ lati sa asala fun ẹmi rẹ, ọna Benin Republic lo fẹ gba lọ si orilẹede Germany.

Amọ, ni Cotonou lawọn ọlọpaa Interpol ti mu Igboho nigba to fẹ wọ ọkọ ofurufu lọ si Germany.

Lati igba naa lo ti wa ni ahamọ lori ẹsun pe o wọ Benin Republic lọna aitọ.