Oluwo Wedding Letter: Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo lórí ìgbéyàwó tó fẹ́ ṣe

Oluwo ati Gomina Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Gboyega Oyetola

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti fèsì sí lẹ́tà kan tó gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan lánàá pé Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ń bèèrè fún ogún mílíọ̀nù Náírà lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà láti fi ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin ìlú Kano.

Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Kọmíṣọ́nà ètò ìròyìn àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ará ìlú, Funke Egbemode ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Oluwo ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ náà, ó pọn dandan kí ìjọba náà ó dẹ́kun àwọn oníṣẹ́ láabi láti máa gbé ìròyìn elẹ́jẹ kiri.

Egbemode ní àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan ló ń gbèrò láti fi orí ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun sọ lu ara wọn pàápàá bí ètò ìdìbò sípò gómìnà ti ṣe ń súnmọ́ etílé.

Ó ní ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun ló jẹ ìjọba lógún jùlọ jú ìfẹ́ ẹnìkan ṣoṣo àti pé àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó le ṣe àwọn ará ìlú ní àǹfàní tó sì lè mí ìdàgbàsókè bá ìlú ni Gómìnà Gboyega Oyetola gbájúmọ́, kìí ṣe onínàkúnàá.

Ó fi kun pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí kò fẹ́rán ìjọba tó wà lóde ló ń gbé àhesọ ọ̀rọ̀ ló ṣe ayédèrú lẹ́tà náà.

Kọmíṣọ́nà náà ní àwọn ìlú Iwo ni inú wọn ń dùn sí ìjọba Oyetola lásìkò fún àwọn ohun tí òun ṣe fún wọn lọ́wọ́ yìí lòdì bí àwọn ìjọba tó ti ré kọjá kò ṣe wo ọ̀dọ wọn látẹ̀yìn wá.

Ó tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀ èrò tó gba gómìnà lálejò nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí Iwo ló fa àhesọ náà ṣùgbọ́n àwọn kò ní wo ariwo ọjà àwọn tí kò mọ̀ ju kí wọ́n máa kọ ọ̀rọ̀ irọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára lọ láti dá rúgúdù silẹ̀.

Bákan náà ló wá rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí àwọn tí wọn kò mọ̀ ju láti máa ba ìjọba lórúkọ jẹ́ lọ.

Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo

Iwe kan ti jade sori ayelujara bayii eyi ti ọpọ eeyan ti n sọrọ le lori lori ayelujara bayii.

Iwe naa lo ni akọle aafin Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrashedd Adewale Akanbi lori, eyi ti ontẹ ijọba ipinlẹ Osun si wa nisalẹ rẹ.

Ontẹ ijọba ipinlẹ Osun naa lo fihan pe wọn tẹwọ gba iwe ọhun ni ọọfisi oludamọran pataki si gomina Oyetola, eyi to wa nileesẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.

Iwe yii ni wọn kọ ni ọjọ Kẹjọ osu Keji ọdun 2022 ta wa yii, ti nọmba rẹ si jẹ HIM/TELU 1/14.

Lẹta naa ni wọn fi ransẹ si Gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola, ti akọle rẹ si jẹ ‘ Ifitonileti nipa igbeyawo ati ibeere fun atilẹyin owo.’

Lẹta to n fa awuyewuye

Oríṣun àwòrán, Osun state Government

Ki lo wa ninu lẹta ti ami idamọ Oluwo wa lara rẹ naa?

Ninu lẹta ẹbẹ fun iranwọ owo ati ifitonileti nipa ayẹyẹ igbeyawo naa, lo safihan pe Oluwo fẹ fi ọmọọbabinrin lati ilu Kano to wa lati ile ọba Ado Bayero se aya.

Ninu lẹta naa lo ti fihan pe Ọba Akanbi ṣalaye pe inawo fun igbeyawo naa yoo ju ogun miliọnu naira lọ ninu eyi ti o ti n beere fun iranwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun lati gbe bukata diẹ lara owo yii.

"Mo fẹ mu wa si iranti gomina pe irufẹ igbeyawo bayii laarin gbajumọ ile ọba meji lorilẹede Naijiria, yoo nilo owo gọbọi eyi to fa a ti atilẹyin inawo ati ohun miran fun lilo lati ọdọ ijọba ipinlẹ yii fi ṣe pataki."

Nigba ti BBC kan si agbẹnusọ fun Kabiyesi oriade naa Ibrahim Alli, O ṣalaye pe ọrọ idakọnkọ igbe aye Kabiyesi Oluwo ni ọrọ igbeyawo rẹ jẹ kii ṣe ohun ti awọn le e maa sọ sita.

Àkọlé fídíò, Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

N ko mọ nipa lẹta ti wọn fi n beere N20m lọwọ ijọba Osun - Oluwo

Ọna lati fi idi otitọ mulẹ pe lootọ ni lẹta naa wa lati aafin Oluwo tabi bẹẹ kọ lo jẹ ka kan si Oluwo tilu Iwo lori ọrọ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ọjọ Ẹti, Oluwo ni irọ lasan ni wọn n pa mọ oun nipa iwe ọhun.

O ni oun ko mọ ibi ti iwe ibeere fun owo naa ti wa nitori siginasọ to wa nibẹ, kii se ti oun.

"Se ẹ ri ọwọ mi ninu lẹta naa ni, ko si ọwọ mi nibẹ.

Awọn eeyan ko le ma gbe iroyin ofege sita, lati fi ba orukọ eeyan jẹ.

Wọn ko sẹsẹ maa parọ mọ wa lati fi ba orukọ wa jẹ ni igboro."

oluwo ati gomina oyetola

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1

Awọn ọta gomina Oyetola lo n pa irọ mọ mi tori mo n ti gomina lẹyin:

Bakan naa ni Oluwo tẹsiwaju pe awọn ọta gomina ti wọn jọ n du ọrọ ibo lo seese ko wa nidi ọrọ yii.

"Ọrọ ibo n bọ, bi wọn si se maa n se niyẹn.A mọ ibi ti wọn ti ri iwe ọhun.

Kii se siginasọ mi lo wa ninu iwe naa, n ko si le ma ti ọwọ bọ iwe ti mo ba fẹ ba gomina sọrọ.

Ki wọn lọ wo siginasọ mi lati wo si eyi to wa ninu iwe naa, boya o bara mu.

Mo maa n sọ otitọ pe gomina Oyetola n se daadaa, o n san owo osisẹ, to si n se oju popo.

Mo ni o si yẹ ko wọle fun saa keji, bakan naa aye Oyetola ni mo gba ipo ni ile ẹkọ olukọni tijọba apapọ̀."

Lootọ ni mo fẹ se igbeyawo pẹlu Ọmọọbabinrin ni idile ọba Ado Bayero:

Nigba to n fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni oun n palẹmọ lati se igbeyawo, Oluwo ni eyi ni awọn alatako gbọ, ti wọn fi gbe arumọjẹ siwe naa sita.

"Se ko yẹ ki n se igbeyawo ni, mo gbọdọ ni iyawo.

A ko tii sọ fun araye amọ laipẹ ni a se ayẹyẹ naa, bi o tilẹ jẹ pe a ko tii mu ọjọ."

Ko tii ya ti n kọ iwe sijọba funra rẹ:

Oluwo ni ti akoko ba to, funra oun ni oun yoo kọ iwe sijọba, ti oun yoo si buwọlu lu.

O ni oun yoo tun yan igbimọ ti yoo se kokari eto igbeyawo naa, ti aye yoo si gbọ, ti ọrun yoo si mọ.

Àkọlé fídíò, Oluwo ilu Iwo ba BBC Yoruba sọrọ lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba

Ta ni Oluwo tilu Iwo:

Oluwo ni ọba ilu Iwo ni ipinlẹ Osun, orukọ rẹ si ni Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni.

Ọjọ Kọkanlelogun osu kẹfa ọdun 1967, tii se ọdun marundinlaadọta sẹyin ni Oluwo de ile aye.

Agboole Molasan to wa ni idile ọba Gbaase ni Abdulrasheed Akanbi ti jade, oun si ni ọba Kẹrindinlogun ti yoo jẹ nilu naa.

Osu Kọkanla ọdun 2015 si ni Telu kinni di ọba ilu Iwo amọ ọpọ awuyewuye lo rọ mọ oriade naa.

Lara awọn awuyewuye naa ni bo se kọ olori rẹ akọkọ silẹ, to si tun ni oun fẹ ki wọn maa pe oun ni Emir dipo ọba ti wọn n jẹ nilẹ Yoruba.

Lọwọ lọwọ bayii, ko si ayaba kankan ni aafin fun Oluwo, to si ti fidi rẹ mulẹ fun BBC bayii pe oun ko ni pẹ se igbeyawo.