Mummy GO: Mummy GO ní ẹ̀ṣọ́ ara òun le ra ilé bàbá ẹlòmíì, òun fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ ni

Gbajúgbajà Ajíyìnrere Funmilayo Adebayo, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Mummy G.O. tún ti gbé tuntun yọ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ nígbà tó bá ń wàásù.
Fọ́nrán tuntun mìíràn tó tún gbòde kan báyìí nípa Mummy GO, ní èyí tó tí ń fesi fun àwọn ènìyàn tó ń sọ̀rọ̀ si lórí pé kìí lo ẹ̀ṣọ́ ara.
Nínú fọ́nrán fídíò náà, Mummy GO ní, ní ayé tí òun kọ́kọ́ wá, òun fẹ́ràn láti máa lo ẹ̀ṣọ́ ara púpọ̀ tí òun sì máa ń rà wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀.
- Kìí ṣe ilẹ̀ Afíríkà ni mo wà nígbà tí mo kọ́kọ́ wá sílé ayé - àṣírí ọ̀rọ̀ tuntun rèé lẹ́nu Mummy G.O
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Àsọtẹ́lẹ̀ 2022 àti ìgbésẹ̀ tí Pásítọ̀ Enoch Adeboye fẹ́ gbé lórí ìdojúkọ Nàìjíríà nìyí
- 'Ẹ ṣọ́ ẹnu yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún 2022, àwọn ọlọ́pàá kìlọ̀ fáwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run bí bẹ́ẹ̀ kọ́...'
- 'Kí òpin dé sí ìmọtaraẹni nìkan àti gbogbo ìwà àjẹbánu lórílẹ̀èdè Nàíjíríà''
- Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó já s'ófo lórí ìdìbò 2019
- 'Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà náà máa n ṣàbèwò sí àwọn wòólì, wọn kò lè fòfin de àsọtẹ́lẹ̀ ọdún tuntun'
Mummy GO fesi pada fun awọn to ni kii lo ẹṣọ ara:
"Ta ló sọ pé mi ò fẹ́ràn lílo ẹ̀ṣọ́ ara, nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ gbígbé egbògi olóró cocaine, àwọn ohun ẹ̀ṣọ́ ara tí mo kó jọ, le ra ilé bàbá ẹlòmíràn."
"Mo fẹ́ràn kí n máa rà wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ ara tí mo ní nígbà náà, tí a bá gbe lé òdiwọ̀n nísìnyí, yóò tó ọ̀dúnrún mílíọnù náírà."
"Amọ mo jọ̀wọ́ rẹ̀ kalẹ̀ nítorí ìjọba ọ̀run tí gbogbo wa ń wá"
O pẹ ti mo ti n gba idamẹwa lọwọ asẹwo ati adigunjale:
Ajihinrere naa tẹ siwaju pe awọn ọmọ ijọ oun ko padanu ohunkohun gẹgẹ bi oun ti se sẹyin, ni aye ti oun kọkọ wa.
O ni "Ki lẹ ti i padanu, ẹ ko ti i padanu ohunkohun rara, tori naa lẹ se n mu omulomu, mo ti padanu ohun to pọ ju sẹyin.
Ki eeyan ji laarọ bayii, ko maa gbọ gbọngaun gbọngaun, alaati owo wo lo n de, miliọnu lo n wọle sinu apo asuwọn owo mi nile ifowopamọ si ori foonu mi.
Owo cocaine niyẹn. Mo n lọ si ile igbafẹ lorisirisi, awọn ọmọ to n se oloso yoo jade lọ ni alẹ, o pẹ ti mo ti n gba idamẹwa.
Awọn ọmọ alaristo, awọn ọmọ alasẹwo, wọn maa san idamẹwa fun iya wọn. Mo maa n gba owo lọwọ wọn.
Owo ko tan lọwọ mi ri, ti owo mi nile ifowopamọ ba ku ọgbọn miliọnu naira, maa ma gbọn kiri ni pe ko si owo.
Maa tun ran awọn ọmọ jade pe fun isẹ adigunjale, mo wa ni mo di atunbi, mo fi gboogbo rẹ silẹ, mo wa gba kamu, mo n se bii ọnọ ti iya rẹ n saisan.
Ẹyin tun wa n sọ pe fake, ayederu ni mi, nnkan n se ẹ ni?
Ori rẹ yọ ẹ ti n ko se ogidi, boya n ba ti wa ja ile rẹ ni ole, ki n fi ibọn tu gbogbo ori rẹ danu."
O yẹ kawọn ọlọpaa ti gbe Mummy GO lori awọn ijẹwọ ẹsẹ to n se - Araalu
Mummy GO ni kii lo yẹri eti, ẹgba ọrun tabi ti ọwọ, ti awọn eeyan si maa n lero pe ko nifẹ lati maa lo awọn ẹsọ ara yii ni.
Amọ nigba to wa kede pe oun ti ni awọn esọ ara yii si, ti oun si maa n lo wọn pupọ nigba kan ti oun n gbe oogun oloro, ero awọn eeyan lori ayelujara se ọtọọtọ lori ọrọ naa.
Bakan naa ni wọn tun n fesi lori ohun to sọ pe oun maa n gba idamẹwa lọwọ awọn asẹwo ati adigunjale.
Awọn eeyan kan ni se lo yẹ ki ileesẹ Ọlọpaa gbe Mummy GO nitori funra ara rẹ lo n jẹwọ ẹsẹ to ti da sẹyin.
Awọn eeyan miran ni nigba wo ati ni ọdun wo ni mama oniwaasu yii gbe egboogi oloro Cocaine?
Wọn ni se nigba aye to wa yii ni abi ni aye atijọ to ti wa tẹlẹ, gẹgẹ bo se maa n sọ tẹlẹ?
Awọn miran tilẹ n beere pe gbogbo awọn eeyan ti mama oniwaasu yii ti kọ nisẹ tẹlẹ, ki lo de ti wọn ko fi bọ sita wa kin ọrọ rẹ lẹyin?
Amọ awọn eeyan kan da lohun pe gbogbo awọn to sisẹ ibi tii pẹlu Mummy GO lo ti ku tan nitori pe ati to ti wa tẹlẹ, lo ti sẹ ẹsẹ naa, eyi to fẹẹ to ẹgbẹrun ọdun.

Oríṣun àwòrán, @dramatipeople_/Instagram
Awọn iroyin wo lo ti jade sita nipa Mummy GO tẹlẹ?
Onírúurú fọ́nrán ló ti máa ń jẹ jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó máa ń ti ẹnu Ajíyìnrere Funmilayo Adebayo jáde, pàápàá lórí ìjọba ọ̀run, tó sì máa ń fa awuyewuye láàárín àwọn ènìyàn.
Nínú àwọn fọ́nrán yìí ni Mummy GO ti sọ pé òun ti wá ilé ayé nígbà kan rí àti pé kìí ṣe ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni òun wà nígbà náà.
Bakan naa lo tun máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe lo ìgbésí ayé aláìnígbàgbọ́ lásìkò náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tilẹ̀ máa ń sọ pé Mummy GO, tó ni ilé ìjọsìn Rapture Proclaimer Evangelical Church of God, kò mọ ohun tí ó ń sọ à ti pé ó nílò ìtọ́jú dókítà.
Ta ni Mummy GO?
Funmilayo Adebayo ni orúkọ tí ìyá àti bàbá sọ ọ́ ṣùgbọ́n Mummy GO ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ ọ́ sí nítorí àwọn ìwàásù rẹ̀.
Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, ọsù kẹfà ọdún 167 ni wọ́n bi. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ekiti ni.
Òun ni olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn Rapture Proclaimer Evangelical Church of God tó wà ní Iyana Ipaja ní ìpínlẹ̀ Eko.
Nínú oṣù kìíní ọdún 2021 ní ìràwọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn lórí ẹ̀rọ ayélujára nígbà tí àwọn ìwáàsù rẹ̀ tó dá lórí wíwá ìjọba ọ̀run gba ìgboro kan.
Mummy GO ti ṣe ìgbéyàwó tí Ọlọ́hun sì fi àwọn ọmọ tá lọ́rẹ.




















