New Year Prophesy: Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà naa máa n ṣàbèwò si awọn wòólì wón ko le fofin de àsọtẹ́lẹ̀ ọdun tuntun

New Year Prophesy: Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà naa máa n ṣàbèwò si awọn wòólì wón ko le fofin de àsọtẹ́lẹ̀ ọdun tuntun

Ọpọ awọn oloṣelu, ati awọn agbẹjọro lawujọ ti fi ero wọn han pe lailai, ijọba Naijiria ko le pa iru asẹ ti ijọba Ghana pa lori asọtẹlẹ ọdun tuntun ni orilẹede rẹ.

Ọjọ melo kan ṣẹyin ni ile isẹ ọlọpaa Ghana fi atẹjade kan sita pe gbogbo awọn woli ati pasitọ to ma n ri iran odi lati pa ẹnu wọn mọ dun ọdun 2022, ati pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo foju wina ofin. 'Ẹ ṣọ́ ẹnu yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún 2022, àwọn ọlọ́pàá kìlọ̀ fáwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run bí bẹ́ẹ̀ kọ́...'

Eyi lo mu ki awọn ọmọ Naijiria yii fi ero ti wọn naa han lori nnkan ti ko ni fi seese ni Naijiria.

Ninu ọrọ wọn, agbẹjọro agba Femi Falana, Ebun-Olu Adegboruwa ati Mike Ozekhome ṣalaye pe ọpọ awọn oloṣelu lo ti ba awọn ti wọn pe ni ẹni ẹmi yii mulẹ, awọn ariran, Aworawọ, Ẹlẹbọ, baba alawo ati awọn Wooli nitori naa wọn ko le se ofin kankan ti yoo ba wọn wi.

Ninu ọrọ tirẹ, ọjọgbọn kan ni Fasiti ipinlẹ Eko Dapo Asaju ṣalaye pe ọpọ awọn oloṣẹlu to maa n sa kijokijo tẹle awọn wooli lati gbadura fun wọn to si ni wọn kan n fi asiko wọn ṣofo ni, ati pe Ọlọrun ko le tori eniyan ṣe ohunkohun afi nkan ti o ba wu u lati se funra rẹ.

O ni Ọlọrun yoo fun awọn oludibo ni aaye lai yan adari wọn kii se nitori pe woli kan sọ asotẹlẹ nipa idibo naa.

Aṣaju to jẹ alakoso fasiti Ajayi Crowther ni ipinlẹ Oyo nigba kan ri ati Bishop Theologian ti Anglican Church of Nigeria sọ pe awọn Woli eke maa n kan lo iwoye wọn lati wo saakun nnkan ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba ti ro nnkan meji pọ, wọn a wa pe e ni asọtẹlẹ ọdun tuntun.

O ni awọn asọtẹlẹ gidi si wa ti o jẹ tootọ ti wọn si maa n se itọna fun nnkan ti yoo ṣẹlẹ lọjọ iwaju, ti wọn mọ Ọkan ọlọrun lati kede wahala tabi aburu ti yoo ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Aṣaju tun kilọ fun awọn olori ẹsin lati jina si awọn asọtẹlẹ to le mu idoju ti ba wọn bii ki a maa sọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo jawe olubori tabi oloṣelu ti yoo jawe olubori ninu idibo.

Bakan naa ni Ọjọbọn kan ninu imọ Islamu ni Fasiti ipinlẹ Eko bakan naa Ishiaq Akintola bu ẹnu atẹ lu awọn woli gbajuẹ ti wọn yoo maa fi ọwọ ọtun ati osi wọn ka owo lẹyin ti wọn ba ti fi ọrọ ẹnu wọn lu jibiti awọn alaimọkan to n tẹle wọn.

O ni awọn oloselu ati awọn eniyan miran to nifẹ si ki wọn ma fura si gbogbo nnkan ma n saba tẹle wọn ti wọn si maa n fi wọn se baba wọn ninu oluwa, lati gba imọran tabi itọni ninu ẹmi lori ero ọkan awọn eniyan naa to wa si imusẹ tabi imusẹ ayamọ ẹlomiran.

Akotola gboriyin fun aarẹ orilede Ghana fun agbekalẹ ipinu rẹ lati fofin de ẹnikẹni ti yoo maa sọ asọtẹlẹ to le da wahala silẹ , ko ipaya ba ara ilu tabi fa iku ara ilu lorukọ asọtẹlẹ ọdun tuntun 2022.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete