Dog eat man's private part: Ìgbẹ́ ìdí ni Ajá fẹ́ lọ jẹ, ǹkan ọmọkùnrin olówó rẹ̀ bá wọ̀ọ́ lójú, bí àjá ṣe bù ú jẹ nìyí

Oríṣun àwòrán, Getty Images/ BBC
Awọn olugbe agbegbe nọmba 12 ni adugbo Jebbs, apa ijọba ibilẹ Guusu ni ili Calabar ṣi n ṣe haaa titi di asiko yii ti ọrọ naa ko tii ye wọn bi aja kekere kan ladugbo ṣe ge nkan abẹ olowo rẹ jẹ to si ti ja si iku.
Gẹgẹ bi awọn ara adugbo yẹn ṣe sọ ọ, olowo aja yii, Ani Offiong to wa lati agbegbe Ikoneto ni ijọba ibilẹ Odukpani ti mu ọti yo gidi nigba to si pada si ile rẹ to n ta gọọgọọ, o gbagbe lati ti ilẹkun.
Iroyin ni tori imutipara yii, Ani Offiong tọ sara o si yagbẹ sara bo ṣe na gbalaja silẹẹlẹ ninu palọ rẹ.
"Ni ọkan lara awọn aja rẹ to gboorun igbẹ to si dun mọ ọ nimu ba wọle to si lọ jẹ igbẹ. Ni aja ba tun ri nkan ọmọkunrin Ani Offiong afi hamm, to gbe e hanu to si jẹ ohun naa bii pe ara igbẹ to n jẹ ni.
Akọbi ọmọ arakunrin yii, Offiong Offiong Ani to ba BBC sọrọ ṣalaye pe oun ko si nile nigba ti iṣẹlẹ yii ṣugbọn nigba ti oun yoo pada de ni mọlẹbi rẹ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun un.

O ni koda wọn ti pa aja naa ti wọn si ti sọ ọ nu.
Etim sọ fun Akọroyin wa pe Babalawo ni Ani Offiong Offiong pe ẹgbọn baba rẹ lo si fun un ni aja naa lati tọ.
"Aja meji ni baba naa ni, Tiger lorukọeyi to tobi ju, kekere yii ni ko lorukọ kankan ohun si lo bu u jẹ nitori a ri ẹjẹ lẹnu rẹ ati imu rẹ".
O ṣalaye pe "nigba ti Ọnkuu mi figbe ta, mo gbiyanju lati wọle pẹlu ero pe awọn adigunjale lo wọ le lati ṣe e ni ọṣẹ amọ ibi idi rẹ lo n nawọ si ti mo si ri ẹjẹ mo ba tun sa jade".

Etim fi kun un pe awọn alabagbe wọn kan tilẹ wọ inu ile ti wọn gbiyanju lati doola ẹmi arakunrin naa amọ nigba ti wọn yoo fi nu ẹjẹ ara nkan ọmọ ọkunrin rẹ kuro tan ki wọn si gbe e lọ si ile iwosan, oju na lo ti dakẹ.
"Ilẹ ti su gan lalẹ ọjọ naa ati pe iru akoko opin dun to jẹ, o nira lati ri ọna ati gbe e lọ si ile iwosan gbogbo awọn ile iwosan gan ti tilẹkun lasiko alẹ to bọ si".
Etim ni ọjọ keji ni wọn sin oku rẹ ni iboji Hawkins ni iha Guusu ilu Calabar.
Arabinrin Irene Ugbo to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Cross River sọ pe wọn ko fi ọrọ yii to awọn ọlpaa leti.
"Mi o gbọ nipa iṣẹlẹ naa rara, mi o dẹ ro pe ẹka wa to wa ni Calabar-South gan gbọ nipa rẹ, wọn o ba ti fi ọrọ naa to wa leti".

















