Ghanaian inmate bit off testicles: Ẹlẹ́wọ̀n kan wọ gàù lẹ́yìn tó gé kórópọ̀n ẹlẹ́wọn míràn

Jafaru Boakye ti wọn ge koropọn rẹ

Oríṣun àwòrán, Ghana police

Ọkunrin ẹlẹwọn kan tun ti da ọran mọ eyi to gbe de ọgba ẹwọn , lẹyin to ge koropọn nkan ọmọkunrin ẹlẹwọn bi tiẹ lasiko ija to waye laarin wọn.

Afurasi naa, Awudu Abdulai ni wọn fi ẹsun kan pe o fi eyin ẹnu rẹ ge nkan ọmọkunrin akẹẹgbẹ rẹ, Jafaru Boakye jabọ ninu yaara ọgba ẹwọn ilu Ashanti, lorilẹ-ede Ghana.

Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ naa waye.

Ko sẹni to ti i mọ koko nkan to fa ija laarin awọn mejeeji, ṣugbọn nigba ti wọn o fi la wọn nija, Jafaru ti farapa labẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Tafo Pankrono ni agbegbe Ashanti, to n mojuto iṣẹlẹ naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ.

Ẹni ti wọn ge nkan ọmọkunrin rẹ, Jafaru wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, to si ti n gba itọju nilewosan bayii.

Bakan naa ni wọn tun ti fi awọn ẹsun tuntun kun eyi to gbe Awudu to ge nkan ọmọkunrin de ọgba ẹwọn tẹlẹ, ti yoo si di eero ile ẹjọ.