Alleged rape: Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdún 64 tó fi ìpá bá ọmọ ọdún méjì lòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, ogun state police
Ọwọ ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgọta kan, Ayotunde Taiwo ti wọn fi ẹsun kan pe o ba ọmọ ọdun meji ni ibalopọ.
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Ogun tẹ Taiwo, ni agbegbe Agbado, lẹyin ti iya ọmọdebinrin naa lọ ọ fi ẹjọ sun nileeṣẹ ọlọpaa lọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi, sọ ninu atẹjade kan pe, iya ọmọ naa sọ fun awọn ọlọpaa pe oun deedee ṣakiyesi pe ọmọ oun ko le rin daadaa mọ, to si jẹ pe bi oun ṣe n yẹ ara rẹ wo ni oun ri ti ẹjẹ n ṣan jade ni abẹ rẹ.
Nigba to si bi ọmọ naa leere nipa nkan to ṣẹlẹ, ọmọ na ọwọ si ile to kọju si ile wọn.
Nigba ti iya ọmọ naa sare de ile ọhun, o ba afurasi naa to n fọ ṣokoto awọtẹlẹ rẹ to ni ẹjẹ lara, eyi to fihan pe o ṣẹṣẹ ni ibalopọ pẹlu ọmọ ọdun meji naa tan ni.
Lọwọlọwọ, wọn ti gbe ọmọdebinrin naa lọ si ileewosan fun itọju.
Bakan naa ni ksmisanna ọlọpaa fun ipinlẹ Ogun, Edward Awolowo Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn o gbe afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n pese atilẹyin fun mọlẹbi, eyi to wa ni Ọta, fun iwadii ati fifi oju rẹ ba ile ẹjọ.



















