Admin staff raped college student: Iléeṣẹ ọlọpàá mú Olawale Jamiu, ti iléèkó College of Health lorí pé o fipá bá akẹkọọ lò pọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police, ogun state
Okan lara awan osise ọgba ileẹkọ College of Health Technology lo ti ko si gbaga awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun latari ẹsun ifipabanilopọ.
Olawale Jamiu ẹni odun mọkandinlogoji naa ni wọn ni o fipa ba akẹkọọ ti awọn agbofinro fi orukọ bo lasiri naa lo pọ.
Ileesẹ ọlọpaa ti Ilese Ijebu ni awọn mu ọkunrin naa lẹyin ti awọn alasẹ ile ẹkọọ naa mu ẹjọ wa.
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Akintoye àti èèyàn 1m míì ń lọ àpéjọ UN lórí ìyapa Nàíjíríà
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- GGoriola Hassan, má pe ara rẹ ní ọba Imobi-Ijebu mọ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́... - Ilé aṣòfin Ogun
Wọn ni akẹkọọ naa fẹ wa gba faili eto ẹkọ rẹ ni nigba ti Jamiu Olawale fipa ba a lo pọ.
Awọn alasẹ ileẹkọ naa ni kete ti isẹlẹ yii sẹ ni akẹkọọ naa fi to awẹn alasẹ leti.
Oga agba ileesẹ Olopaa ekun yii ni Ilese Ijebu, Amuda Ajibola si pase pe ki wọn lọ mu ẹni ti a fẹsun kan naa.
Saaju ni wọn ni ọkunrin naa kọkọ parọ pe oun ko se bẹẹ sugbọn nigba ti o ri atẹransẹ to fi n bẹ ọmọbinrin to fipa ba lo pọ naa ni ọwọ rẹ jabọ.
Ni bayii, wọn ti mu ọmọbinrin naa lọ sile iwosan ni Ijebu Ode fun itaju to peye.
Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Awolowo Ajogun ti pask pe ki wọn fa iwadii ẹjọ naa le ẹka ọtẹlẹmuyẹ lọwọ.
Atejade ti Abimbola Oyeyemi tojẹ agbẹnusẹ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi sita ni o ti ni ni kete ti iwadii ba ti pari ni wọn yoo foju ba ile kjọ bi o ti yẹ.













