Pakistan Blasphemy: Ìjà ẹlẹ́ṣìnmẹ̀sìn bẹ́ sílẹ̀ nítorí ọmọ ọdún mẹ́jọ tó tọ̀ sí ilé kéwú

Oríṣun àwòrán, other
Ọmọ ọdun mẹjọ kan ti wa ninu ewu idajọ iku lori ẹsun pe o tọ si ile ikawe ile ijọsin kan.
Lọwọlọwọ bayi ọmọdekunrin ẹlẹsin Hindu yi wa ni abẹ aabo ọlọpaa ni Pakistan.
Lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o mọọmọ tọ sara ninu ile ikawe ile ijọsin.
Ọmọde yi ni ẹni tọjọ ori rẹ kere julọ ti wọn fẹsun kan pe o tabuku ẹsin ni ilẹ naa to se pe ijiya iku lo so mọ ẹsẹ yi.
Wọn fi ẹsun kan pe o mọọmọ tọ si ori itẹ ninu ile ikawe Madrassa ti wọn ko awọn tira si losu to kọja.
Awọn mọlẹbi ọmọdekunrin yi ti sa asala fun emi won.
Nigba ti ọpọ awọn ẹlẹsin Hindu ni Punjab naa si sa asala fun ẹmi wọn.
Eyi waye lẹyin ti awọn musulumi kan ya bo ile ijọsin awọn Hindu lẹyin ti ile ẹjọ gba oniduro ọmọdekunrin naa ti wọn si ni ko maa lọ sile.
Ọrọ yi le debi pe wọn ti ni kawọn ọmọọgun lọ si adugbo isẹlẹ yi lati le daabo awọn eeyan.
Lọjọ Abamẹta, eeyan ogun ni awọn agbofinro mu lori ẹsun pe wọn dana sun ile ijọsin Hindu.
Ọkan alara awọn mọlẹbi ọmọ yi to foripamọ ba awọn akọroyin sọrọ.
O ni ''ọmọ yi ko tiẹ mọ nipa ẹsun itabuku ẹsin ati pe ko tiẹ yee bayi ohun ti o jẹ ẹsẹ rẹ ati idi ti wọn fi fi si ahamọ fọsẹ kan''.
O salaye pe " A ti fi sọọbu wa ati isẹ wa silẹ salọ.Gbogbo wa lẹru n ba wa pe wọn le wa gbẹsan nipa ikọlu si wa.A o fẹ pada si agbegbe yi.''
O ni awọn ko lero pe wọn yoo gbe igbesẹ kan to jọju lati le mu awọn to wa nidi ikọlu yi tabi daabo bo awọn ẹya ti ko lẹnu lọrọ lagbegbe ọhun.
Nise ni ọrọ yi se awọn amọfin ni kayeefi lori bi wọn se fi iru ẹsun yi kan ọmọde.
Ramesh Kumar, agbẹjọro to si tun jẹ olori ẹka alasẹ Hindu ni ''ikọlu tawọn eeyan se si ile ijọsin Hindu ati ẹsun itabuku ẹsin Islam ti wọn fi kan ọmọde yi ya mi lẹnu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari, to bá fi pánpẹ́ ọba mú Akitoye, ohun tá ṣe rèé - Ẹgbẹ́ Ajìjàgbara ṣèkìlọ̀
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Sunday Igboho fi ń ṣe ẹjọ́ ní Benin - Femi Falana
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Èèmọ̀! Àrùn tuntun Marburg, tó le ju Covid-19 lọ gbòde lágbàáye
O ni o le ni ọgọ́run idile Hindu to ti sipo pada nitori ibẹru lori isẹlẹ yi.
O wa parọ́wa si ijọba lati pese aabo to peye.
Ikọlu sawọn ile ijọsin Hindu lẹnu ọjọ mẹta yi pọ si nitori awọn alakatakiti ẹsin ati awọn to gba nkan mii mọ ẹsin.















