Sokoto Food Poisioning: Èèyàn méjì tó tọ́ oúnjẹ náà wò dèrò ilé ìwòsàn

Kọmísọ́nà ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Sokoto, Dókítà Ali Inname ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́jọ́ Isegun pé, àwọn ènìyàn mẹrìnlélógún ló kú nínú ìdílé kan lẹ́yìn tí wọ́n jẹ májèlé nínú oúnjẹ.
Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní abúlé Danzanke ni ìjọba ìbílẹ̀ Isa, lẹ́yìn ti wọ́n jẹ́ oúnjẹ tí wọ́n bu eroja ajilẹ to dabi iyọ si dipo ojulowo iyọ.
"Gbogbo ẹbí tó jẹ́ oúnjẹ tí wọ́n fi eroja ajilẹ naa, ti wọn n pe ni Gishirin Lalle ni èdè Hausa si ló kú.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọba alayé kan àti gómìnà kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi, kí n tó fẹ́ Mr Lawal - Lizzy Anjorin
- Goriola Hassan, má pe ara rẹ ní ọba Imobi-Ijebu mọ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́... - Ilé aṣòfin Ogun
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Akintoye àti èèyàn 1m míì ń lọ àpéjọ UN lórí ìyapa Nàíjíríà
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
Àwọn méjì tí kò kú nínú ẹbí náà lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ni àwọn ti wọ́n kan tọ oúnjẹ náà wò, sùgbọ́n wọ́n sì wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti n gba ìtọ́jú báyìí.
"Gbogbo ìgbìyànjú wa láti gba ẹ̀mí àwọn tó jẹ oúnjẹ náà nínú ẹbí ọ̀hún la, ló já sí pàbó", gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Inname ti ṣàlàyé.

Oríṣun àwòrán, NCDC
Kọmísọ́nà naa wa rọ àwọn ará ìlú láti kọ́ ẹ̀kọ́ lára ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, kí wọ́n sì ṣọ́ra fún irú àwọn nǹkan to jọ ma májèlé, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n sì ko kúrò ni sàkání àwọn ènìyàn ti kò mọ̀.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti maa kíyèsí àwọn ẹbí wọn, kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ aburu yìí máa ba wáyé mọ́.
Ó ní "ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú mọ̀ pé, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ nǹkan ti àwọn ará ìlú le dènà, bákan náà ni kìí ṣe ààrùn tó le ma tàn ká.
Iṣẹ̀lẹ̀ náà lágbára gidi, kìí ṣe nǹkan ti ẹnikẹni le fi ṣeré."
Inname tún gbà wọ́n níyànjú pé, o ṣe pàtàkì ki àwọn ènìyàn fi ìyàtọ̀ hàn láàrín àwọn oúnjẹ ilé àti àwọn òun èlò oko, bákan náà ni kí wọ́n má wo àwọn ohun èlò ìdáná wọn daradara, ki wọ́n tó lòó.
Ó tẹpẹlẹ mọ́ pé kí àwọn ilé oúnjẹ ri dáju pe wọ́n dènà àwọn esinsin àti kòkòrò lóríṣirísi, ki wọ́n sì maa mójú tó omi àti ohun jíjẹ dáradára.















