PDP Crisis: Ologbondiyan ní ìjà inú ẹgbẹ́ náà kò sẹ̀yìn ìbò 2023, kìí ṣe nǹkan bàbàrà
Iṣẹlẹ to n waye lọwọ ninu ẹgbẹ People's Democratic Party (PDP) jẹ nnkan ti o ma n waye ni gbogbo ẹgbẹ paapaa julọ ti o ba ti sunmọ asiko ti idibo miran n bọ.
Eyi ni alaye Kola Ọlọgbọdiyan, to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP nilu Abuja lasiko ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba.
Kọla Ologbondiyan ni, gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa ni o maa n fẹ ki ipo ẹni ti yoo jẹ alaga ẹgbẹ fun saa miiran bọ sọdọ rẹ, nitori naa gbọmisi-omi-oto to n lọ lọwọ yii yoo bẹ silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gómìnà ìpínlẹ̀ New York ní America kọ̀wé fipò sílẹ̀!
- Ilu Iselu nípìnlẹ̀ Ogun yí èrò rẹ̀ padà lórí oyè tó fẹ́ ẹ́ fi Okorocha jẹ
- Ọmọ ọdún 21 gba ìdájọ́ ikú nítorí ó jalè ni sọ́ọ̀bù oògùn
- Èyí ni àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ gbé lórí aṣojú ìjọba Nàìjíríà tí wọ́n kọlù ní Indonesia
- Kí ló fa àkọ̀tun ìyapa láàrin àwọn ajìjàgbara Yorùbá Nation?
- Aṣọ́bodé lé ọkọ̀ onífàyàwọ̀ wọ àárín ìlú, èèyàn mẹ́fà kú
Bakan naa lo fikun pe àwọn to ti jẹ mínísítà tabi gomina tẹlẹ ti parapọ bayii, lati ri daju pe wọn mu alaafia wọ inu ẹgbẹ ati lati ṣe nnkan ti iwe ofin ẹgbẹ sọ laarin osu mẹrin to ku fun ipade gbogboogbo.
O wa pe fun ifẹnuko awọn ọmọ ẹgbẹ lojuna lati mu ki awọn ọmọ Nàìjíría le bọ nínu oko iya ti wọn wa.
O ni ẹgbẹ ko gbọdọ fi han pe aarin awọn ko gun, ki wọn le mọ pe awọn setan lati dije, sùgbọn ọpọ lo n reti lati ṣe nnkan ti yoo han si gbogbo eniyan.
"Saaju ọdun 2015, iwa jagidijagan ni ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) n hu nitori pe wọn fẹ gba ijọba sugbọn gẹgẹ bi ẹgbẹ to ti sinlu ri, ẹgbẹ oṣẹlu PDP mọ ilu tò nitori pe nigba ti wọn wa nipo aye, ko nira fun ara ilu bi asiko yii"
Ologbondiyan ni gbogbo nnkan ti ẹgbẹ oselu APC sọ pe awọn yoo se lasiko ti wọn n pologo ibo, lati bi ọdun mẹfa si asiko yii, ko si eyi ti wọn mu ṣẹ.
Akọwe Ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP ni "ti a ba ni ki a gbe ẹgbẹ oṣelu APC si ori iwọn, òdo pọnbele ni wọn gba nitori ko si larija aseyọri kankan paapaa julọ lori ọrọ eto aabo.
Ologbọndiyan naa oju ọmọ Naijiria ti la ju pe ki eniyan maa se nnkan to pinu lati ṣe i ko ba ṣe awọn ọmọ Naijiria yoo yọ danu.
O rọ awọn ọdọ ati obinrin lasiko yii lati wa dije nitori pe ẹgbẹ PDP ti fi aaye silẹ lati mu ki nnkan ki o rọrun fun wọn.
O ní ni asiko yii, owo ìkanlẹkun nikan ni PDP n gba bayii lojuna lati mu ki awọn eniyan le darapọ mọ ẹgbẹ, ki wọn si le kopa ninu eto oselu.

Agbo PDP ń gbóná janjan, ìpàdé àwọn gómìnà lórí Secondus forí ṣánpọ́n

Oríṣun àwòrán, PDP Facebook
Ibi ti ọrọ alaga ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party,Uche Secondus yoo ja si ko ti foju han pẹlu bi ipade awọn Gomina ẹgbẹ naa ko se fẹnu ko lori ọrọ rẹ.
Nibi ipade to waye ni Abuja lọjọ Aje lo yẹ ki wọn ti sọ boya Secondus yoo si wa lori ipo tabi ki wọn yọ saaju ipade gbogbogbo ẹgbẹ losu Kọkanla ọdun.
Amọ a gbọ pe ipade igbimọ amusẹya ẹgbẹ naa ko panupọ sọna kan lori ọrọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
Ninu awọn ọmọ igbimọ naa, awọn mẹfa kan ni ko kọwe fipo silẹ tawọn iyoku ko si faramọ, amọ eyi ko tan sibẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ to wa nile asojusofin naa ko fimọ sọkan lori iyọninipo Secondus.
Bi a ko ba gbagbe lỌ́jọbọ to kọja yii ni igbimọ majẹkobaje ẹgbẹ da si ọrọ awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ meje to kọwe fiposilẹ.
Ninu awọn to lewaju ki Secondus fipo silẹ ni Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, to ni Secondus n pete pero lati tun dije dupo alaga lasiko ipade apero ẹgbẹ to n bọ lọna ni.
Lẹyin ti wọn se eleyi tan, wọn ba awọn akọroyin sọrọ, ti wọn si ni awọn yoo jiroro laarin ọrọ mẹta lori bi wọn yoo se yanju aawọ to n koju ẹgbẹ naa.
Abalọ ababọ ijiroro yi ni eleyi taa tun gbọ pe wọn ko ti fẹnu ko lori boya Secondus yoo si wa lori oye tabi ko ko ẹru rẹ kuro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.
Ni ọjọ Aje yii kanna, awọn Gomina kan ti wọn wa lẹyin Secondus ti Aminu Waziri Tambuwal Gomina ipinlẹ Sokoto lewaju wọn, si duro gbọin lẹyin Secondus pe ko pari saa rẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.
Tambuwal, lasiko to n ba awọn akọroyn sọrọ ni awọn yoo si tẹsiwaju pẹlu ipade naa, tawọn yoo si yanju ọrọ ni tunbi n nubi.
Nibi ti gbogbo eleyi ti n waye naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ yii kan ti se iwọde pe dandan ni ki Secondus fipo silẹ gẹgẹ bi alaga.
Niwaju olu ileesẹ ẹgbẹ naa tii se Wadata Plaza, ni iwọde ifẹhonuhan yii ti waye.
Labẹ asia ikọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Save PDP group mii, wọn ti ko ara wọn jọ pe ki Secondus fipo silẹ nitori pe ko kaju osunwọn.
Lori gbogbo isẹlẹ yii, ki wa ni Secondus sọ?
Saaju ka to sọ nkan ti Secondus naa sọ, o tọ ka fi lelẹ pe Gomina Seriake Dickson tipinlẹ Bayelsa wa lara awọn to duro bi ike lẹyin Secondus.
Bẹẹ naa ni awọn Gomina kan ninu ẹgbẹ ni dandan, ki Secondus pari saa rẹ gẹgẹ bi alaga ati pe ipade gbogbo gboo ẹgbẹ nikan lo lagbara lati yọ ni ipo.
Ipade gbogboogbo yii lawọn to fẹ yọ Secondus lawọn ko le duro de nitori Secondus yoo fidi ẹsẹ rẹ mulẹ nipo alaga.
Ninu atẹjade tiẹ, Secondus sọ pe oun ko se nkankan to yẹ ki wọn fi yọ kuro nipo alaga.
O fi ọrọ yi sita ninu atẹjade to pe akori rẹ ni ''Idi ti mi o le fi fipo silẹ''
- Ìdí rèé táwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà fi wà láhámọ́ títí di ọjọ́ Ajé - Amòfin Yomi Aliyu
- Wo ìgbésẹ̀ tuntun tí DSS ń gbé láti dojú béèlì àwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà bolẹ̀
- Ọwọ́ FBI yóò tẹ Abba Kyari, òǹyẹ̀ kankan kò lè yẹ̀ ẹ́ - Femi Falana
- Akeugbagold sọ̀rọ̀ lórí bóyá ṣíṣe àjọ̀dún Hijra tọ̀nà àbí bẹ́ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìkéde ọjọ́ ìsinmi
Ike Abonyi to jẹ agbẹnusọ rẹ lo fi sita lọjọ Aje ni Abuja.
Ni soki nkan ti Secondus sọ ninu atẹjade naa ni pe, ki awọn eeyan perete to n pe fun ifiposilẹ rẹ jade sita lati wa sọ fun araye idi ti wọn fi fẹ ki oun si ipo silẹ.
Ipade awọn Gomina si n tẹsiwaju loni tii se ọjọ Isẹgun.




















