Domestic Violence: Joy tún gún òǹlàjà, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ẹni tí wọn jọ ń jà, ní ọ̀bẹ lọ́wọ́ òsì

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police
Ija ko si ni sọọsi, Sadura , ki n se amin ni.
Amọ ọrọ kor i bẹẹ nile ijọsin kan nibi tawọn obinrin meji ti gbe pẹrẹgi ka ina nitori ọkunrin.
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu arabinrin kan to da omi gbigbona soju iyawo ile kan, to fẹsun kan an pe o n yan ọkọ rẹ lale.
Obinrin naa, Joy Sunday, ẹni ọdun mẹtadinlogoji la gbọ pe ko bu ọwọ ile ijọsin ti wọn ti lọ se aisun wọ arabinrin Justinah Ameh, ko to da omi gbona si loju.
Atẹjade lati ọdọ alukoro ileesẹ ọlọpaa Abimbola Oyeyemi salaye pe, ẹgbọn Justinah lo fi ọrọ naa to awọn leti lagọ ọlọpaa to wa ni Agbado.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Ta ni èṣù láàrin ìjọ Ọlọ́run àti Hushpuppi? - Daddy Freeze bèèrè
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abba Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- Buhari ná ₦5trn lórí ètò àbó síbẹ̀ Boko Haram, agbébọn pa 11,420 ọmọ Nàìjíríà - Ìwádìí
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
Gẹgẹ bo ti wi, o ni ile ijọsin Spring of Life Global Ministry to wa ni Giwa ni Agbado, ni isẹlẹ yi ti waye.
O ni nigba ti oun n gbiyanju lati di arabinrin naa lọwọ mu, n se lo gun oun lọbẹ lọwọ osi.
Nigba tawọn ọlọpaa n fọrọ wa afurasi naa, Joy Sunday lẹnu wo, o ni ọjọ ti pẹ ti Justinah ti maa n fẹsun kan oun pe oun n yan ọkọ rẹ lale.
O ni oun ti igbiyanju lati yọ ero yii kuro lọkan rẹ, amọ ko sinmi lati maa fẹsun kan oun.
O sọ pe lọjọ taa n wi yii, Jistinah lo bẹrẹ si ni pariwo le oun lori nile ijọsin, to si n rọjo epe loun lori.
Joy ni ibinu yii lo mu ki oun lọ gbe omi gbona ka ina nile, ti oun si pada wa lati da lu lori ni ile ijọsin.
Nigba ti awọn ọlọpaa beere lọwọ rẹ pe se lootọ lo n yan ọkọ Justinah lale, o ni ko si oun ti oun ko le fi bura pe ko si oun to jọ bẹẹ laarin awọn.
Lọwọlọwọ bayi, Justinah n gba itọju nile iwosan.
Kọmisana ọlọpaa Edward Ajogun ti ni kawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii ni kiakia, lati le fi gbe ọrọ naa sile ẹjọ.

Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, NigerianArmyHQ
Awọn janduku agbebọn tun ti ji ẹbi kan to n rinrin ajo lopopona Ewu-Ayetoro Ekiti ni ijọba ibilẹ Ido/Osi nipinlẹ Ekiti.
Awọn janduku naa ṣekupa olori ẹbi naa, wọn si gbe iyawo ati ọmọbinrin rẹ lọ.
Iroyin sọ pe ẹbi naa n rinrin ajo bọ lati ibugbe wọn niluu Eko wa si ipinlẹ Ekiti fun ayẹyẹ isinku kan ti yoo waye niluu Ewu Ekiti, ki wọn to ko sọwọ awọn ajinigbe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abba Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- Buhari ná ₦5trn lórí ètò àbó síbẹ̀ Boko Haram, agbébọn pa 11,420 ọmọ Nàìjíríà - Ìwádìí
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
Ẹnikan ti o mọ nipa iṣẹlẹ ọhun sọ pe eeyan mẹrin lo wa ninu ọkọ Lexus tawọn ẹbi yii fi rinrin ajo naa.
Ẹnikan mori bọ ninu wọn, awọn agbebọn pa baba, wọn si gbe iyawo ati ọmọbinrin kan lọ.
Awọn eeyan awujọ ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ti wa n gbiyanju lati doola awọn meji ti wọn gbe lọ, lọwọ awọn ajinigbe.
Lalẹ ọjọ naa lawọn ajinigbe yii kan si ẹbi wọn ti wọn si beere aadọta miliọnu owo itusilẹ lọwọ wọn.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe, loju ẹsẹ ni ọkunrin ti wọn yinbọn fun naa gbẹmi mi.
Abutu ṣalaye pe awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ eleto abo mii bii Amotekun, Nigeria Security and Civil Defence Corps, to fi mọ awọn filante atawọn ọlọdẹ lo ti wọ igbo lọ lati doola awọn ti wọn jigbe lọ.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ni ipaniyan ati ijinigbe jẹ ohun ti gbogbo ọmọ Naijiria gbọdọ fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto abo lati wa ojutuu si.
''Ọta orilẹede Naijiria lawọn ọdaran ajinigbe pawo ati apaniyan yii jẹ.
Ile iṣẹ ọlọpaa ko gbọ tabi mọ bo ya awọn ajinigbe ọhun ti kan si ẹbi lati beere fun owo itusilẹ awọn ti wọn jigbe lọ.
Amọ, ile iṣẹ ọlọpaa ti mu afurasi kan to n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajinigbe lagbegbe Ido Osi nipinlẹ Ekiti.
Ẹwẹ, lọjọ kẹwaa oṣu kẹrin ọdun 2021 yii naa ni awọn agbebọn kọlu Elewu ti Ewu Ekiti, Oba Adetutu Ajayi loju opopona yii kan naa.



















