Sunday Igboho: Banji Akitoye ní ìgbà tí wọn bá tú Igboho sílẹ̀, ni òun yóò padà sí Nàíjíríà

Sunday Igboho ati Banji Akitoye

Olùdásílẹ̀ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akitoye ti kéde pé irọ́ to jìnà sí òótọ́ ni pé àwọn ti fi Sunday Igboho silẹ̀, láti máá dá fi àyà rán wàhálà tó wà nílẹ̀.

Alakoso àgbà fún ẹgbẹ ìlànà ọmọ Oodua ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akitoye lo sọ èyí láti fesì sí ọ̀rọ̀ tó n fò kiri orí ayélujára pé, Baba náà ti na pápá bora lọ si orílẹ̀edè Cotonou nítori ìgbìyànjú ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti mú.

Ó fikun kun pé, wọ́n ni Sunday Igboho nìkàn ló n dá ná gbogbo owó láti ṣe ẹjọ́ ní orílẹ̀-èdè Benin Republic àti ni Naìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bàbá ni lábẹ́ ìdàrí òun, àwọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara lábẹ oníruurú ẹgbẹ́ ní Nàìjíríà àti lókè òkun ló san gbogbo owó pátá ti wọ́n fi ṣẹjọ ni Cotonou, Eko àti Abuja.

Akitoye ni ẹyọ kan ṣoṣo tí kò sí ni abẹ́ ìsàkóso òun ni ẹjọ́ tí wọ́n ṣe ní ìlú Ibadan nípìnlẹ̀ Oyo.

Àkọlé fídíò, Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

Ó ní agbẹ́jọ́rò tó n mójútó tí Ibadan, olóyè Yomi Aliyu lo ṣọ pé kí àwọn fi ọkan silẹ̀ fún òun, sùgbọ́n gbogbo ẹjọ́ tó kú ni Abuja, Eko àti Cotonou àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ́ lábẹ́ àkósò òun, ni wọ́n ń gbọ́ bùkátà rẹ̀.

Lánàá òde yìí ní agbẹjọrò Sunday Adeyemọ olóyè Yomi Aliyu fi àtẹ̀jáde kan síta pé kò sí ẹnikẹ́ni tó n fún Sunday Igboho lówó láti fi ṣẹjọ́.

Bakan naa ni alagba Banji Akitoye ti kede pe ni kété tí wọ́n bá ti dá Sunday Igboho sílẹ̀ ni àtimọ́lé ni Cotonou, ni òun yóò tẹ ọkọ̀ létí padà sí Nàìjíríà.

Akitoye fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, lóòtọ́ ni òun wà ní orílẹ̀-èdè Cotonou sùgbọ́n kìí ṣe pé nítórí ọ̀nà láti sá fún ìjọba Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi àwọn ìwé ìròyìn kan ṣé n polongo.

Nínú àtẹ̀jáde kan ti àdari ìbáràẹni sọrọ rẹ̀, Maxwell Adeleye fọ́wọ́sí lọ́jọ́ Aiku ló ti ṣàlàyé pé, olóyè Akitoye wà ni òrílẹ̀-èdè Cotounou láti dári àti láti mójútó bí àwọn agbẹ́jọ́rò rẹ̀ yóò ṣe tún Sunday Igboho silẹ láhàmọ́.

Akitoye ni bi ọrọ ti Igboho náà ni, kò sí ẹ̀sẹ̀ kankan ti òun ṣẹ ìjọba Nàìjíríà tí wọn yóò fi máa wá òun ká láti mú tabi maa fi ṣe ẹlẹ́yà.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

Gẹ́gẹ́ bi àkọni, Akitoye ni òun jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ni kété tí ìjọba Benin bá ti fi Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ni oun yóò padà sílé láti wá tẹ̀síwájú lórí ìjàgbàrà Yoruba Nation.

" Èmi, gẹ́gẹ́ bi ààrẹ àgbà pátápátá, ọ̀jọ̀gbọ́n Wale Adeniran to jẹ́ alága Ilana Omo Oodua ni a jọ wà ni orílẹ̀de Benin Republic gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, sùgbọ́n kò sí ẹni tó n sá fún ìjọba."

"Lábẹ́ àkọ́so gbogbo ohun yówù kí ìjọba Nàìjíríà má pínu fún mí, mó fẹ́ sọ láì fòyà pé, màá pàdà sí Nàìjíríà ni kété tí wọ́n bá tí tú Sunday Igboho sílẹ̀"

" Mò ń fí àsìkò yìí sọ fún gbogbo ọmọ Yorùbá nílé, lóko àti lẹ́yìn odi pé, kò sí èwu lóko, kí ẹnikẹni má fòyà, mí o sálọ síbi kankan, Bí iná o bá tán lásọ ẹ̀jẹ̀ kìí tá léékána."

Sunday Igboho: Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye ṣàlàyé ìdí tó fi kúrò ni Nàìjíríà ni àsìkò yìí

Oríṣun àwòrán, Yomi Aliyu