Nigeria insecurity: David Jemibewon faraya lórí báwọn jàǹdùkú ṣe ń borí ọmọogun Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọsilẹ sọ pe ijọba Aarẹ Muhamamadu Buhari ti na owo to le ni tiriliọnu marun naira lori eto abo lati igba to ti gori aleefa lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2015.
Amọ akọsilẹ ọhun ṣalaye pe, bo tilẹ jẹ pe ijọba Buhari ti na owo tabua yii lori eto, ẹgbẹrun mọkanla eeyan ati okoo le ni irinwo (11,420) lawọn ọmọ Naijiria ti Boko Haram atawọn darandaran ti ṣekupa laarin ọdun mẹfa ti Buhari di aarẹ.
Ajọ to n ṣe iwadii lori ọrọ abo ni Naijiria, Nigeria Security Tracker, ajọ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ati ajọ Amnesty International lo gbe akọsilẹ jade.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abaa Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́rin ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìwádìí Abba Kyari àti Ramoni Igbalode
- Hushpuppi ló fi àwọn 'messages' orí fóònù rẹ̀ hàn FBI tí wọ́n fi rí àrídájú lórí ìwà gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí Abba Kyari hù
- Èèmọ̀ rèé o! Àrá sán pa èèyàn 17 níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ọkọ ìyàwó farapa
- Ìdí tí wọ́n fi ń pè mi ní Maradona rèé- Ibrahim Babangida
- Tú ajá rẹ sílẹ̀, kí o fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura ní ìpínlẹ̀ Oyo
Laipẹ yii ni ile aṣofin agba niluu Abuja tun ṣẹṣẹ buwọlu afikun owona fun eto abo, N714.5bn ti Buhari gbe lọ siwaju ile.
Owo to le ni tiriliọnu mẹta naira, N3.11tn lo ti ba owo oṣu ati awọn nkan mii lọ lati ọdun 2016 di asiko yii.
N830.11bn ni owo ti ijọba ti na fun awọn akanṣe iṣẹ ni ẹka eto aabo ni akoko yii bakan naa.
Owo to le ni tiriliọnu kan naira ni ijọba Buhari tun na lati ra baalu ijagun atawọn nkan ijagun miran.
Amọ, pẹlu gbogbo owo gọbọi ti ijọba APC ti na lori eto abo yii, kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si lọrọ naa.
Ajagun fẹyinti to jẹ gomina tẹlẹ ri lapa iwọ oorun guusu Naijiria, Agagunfẹyinti David Jemibewon lo ti wa bu ẹnu atẹ lu bawọn Boko Haram atawọn janduku ṣe n pa ọmọ Naijiria, ti ileeṣẹ ologun si n ni ijakulẹ pẹlu wọn.
O kere tan ogun ọmọgun ofurufu Naijiria lo padanu ẹmi wọn laarin oṣu mẹta, ti baalu awọn ọmọgun si ti ja lulẹ nigba mẹta.
''Ọrọ eto abo ni Naijiria ti buru debi pe awọn eeyan n bẹru lati rinrin ajo.
Eyi si ti ṣe akoba fun ọpọlọpọ nkan bi awọn to fẹ ṣe iṣẹ oko lati gbin nkan ọgbin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Eyi si ti da omi tutu si awọn ọmogun gan an lọkan pẹlu bi awọn janduku yii ṣe n pa awọn akẹgbẹ wọn.
Nkan o fara rọ ni Naijiria lori eto abo, ijọba gbọdọ wa nkan ṣe si ọrọ yii ni kiakia."


















