Oyo law unchained dog owner arrest: Tú ajá rẹ sílẹ̀, kí o fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, @others
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti ṣofin pe ẹnikẹ́ni tí aja rẹ ba bu eeyan jẹ nipinlẹ naa yoo fi aṣọ penpe ro oko ọba.
Ṣugbọn ẹni tun le lanfaani lati san ẹgbẹrun lọna ọta le lugba owo naira din mẹwaa din mẹwaa.
Abẹnugan ile, Họnọrebu Adebo Ogundoyin ṣalaye pe ofin yii jẹ ọkan lara mẹtalelaadọrin ti ile igbimọ aṣofin ti ṣe eyi ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti buwọlu.
- Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Osun bínú yabo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ tó gba ẹ̀mí eèyàn ní Iree
- Ọ̀rẹ́bìnrin kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó gún "Sugar daddy" rẹ̀ pa
- Bí ènìyàn Ọ̀ọ́dúnrún ṣe fò ṣán'lẹ̀ kú rèé torí ààrùn onígbà méjì ní Kano ati Jigawa
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wa ẹnu lé ìyàwó ọmọ Ààrẹ Buhari torí àwọn aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ tó ṣí ara sílẹ̀
- Ààrẹ NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya jáde láyé lẹ́ni ọdún 73
Ofin lori ọsin ajá jẹ ofin ti ọmọ ile, Họnọrebu Wùnmi Olajide ṣagbatẹru rẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Họnọrebu Oladeji ṣalaye pe owo itanran fun olowo ti ko ba le dari aja rẹ bi o ti yẹ bẹrẹ lati ẹgbẹrun lọna ọgọrun tabi oṣu mẹfa lẹwọn.
Aṣofin Oladeji sọ pe ẹnikẹni ti ko ba sanwo itọju ẹni tí aja bujẹ yoo san N250,000 tabi ko fi ẹwọn oṣu mẹfa jura.
"Bakan naa, ẹnikẹni ti ko ba gbabẹrẹ fun aja rẹ yoo san ẹgbẹrun lọna igba owo itanran tabi ki o fẹwọn oṣu mẹfa ṣara rindin.
A n fi asiko kepe awọn ti ọrọ kan lati ṣe ilanilọyẹ fawọn araalu lori ofin tuntun yii.
Ẹwẹ, igbakeji ọga ọlọpaa ni Naijiria, Aishatu Abubakar ti sọ pe ofin tuntun yii yoo jẹ ki awọyn to ni aja máa moju to wọn.
O ni ofin naa yoo dena ki aja maa bu awọn jẹ ati ki aja maa rin kaakiri.
- Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- A ti mú afurasí darandaran méjì tó ń da màálù tó kan ọmọ oṣù mẹ́ta pa- Ọlọ́pàá
- Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò
- Níbo ló kù tí Messi yóò lọ báyìí?
- Kò sí olóṣèlú kankan tó ń pàṣẹ fún wa pé kí á máa ti aráálú mọ́lé- DSS















