Boko Haram Repentants: Ológun ní ebi, èdè-àìyedè àti àìlera ló mú káwọn afẹ̀míṣòfò náà túúbá

Awọn ikọ Boko Haram to ronupiwada

Oríṣun àwòrán, Facebook/HQ Nigerian Army

Ko din ni 1,081 ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, awọn Ọga diẹ ati ẹbí wọn to tẹrí ba fun awọn ọmọ ogun Naijiria lábẹ́ ikọ Operation Hadin Kai.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti awọn ọmọ ogun naa kọlu wọn ni ibùba wọn ni Ìwọ̀-oorun Ariwa Naijiria.

Eyi waye nitori bi ebi, ede aiyede, ati ipenija ilera se mu ìnira ba awọn agbesunmọmi naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, oludari ẹka iroyin nileesẹ ologun, Ọgagun Onyema Nwachukwu sọ pe wọn tun gba àwọn nkan ijagun lọwọ àwọn agbesunmọmi to tẹrí ba ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni Olori àwọn to ma n ju ado oloro fun Boko Haram, Musa Adamu ati Igbakeji rẹ, Usman Adamu pẹlu ẹbí wọn ti yọnda ara wọn fun ikọ ọmọ ogun Hadin Kai nijọba ibilẹ Bama, nipinlẹ Borno.

Awọn ikọ Boko Haram to ronupiwada atawọn ologun

Oríṣun àwòrán, Facebook/HQ Nigerian Army

Nigba to tẹ́wọ́ gba àwọn agbesunmọmi to ronupiwada ọhun lọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, adele ẹka ọwọ́ Keje ileesẹ ologun, Ọgagun Abdulwahab Adelokun Eyitayọ sọ pe iwuri ni bí wọn ṣe ronupiwada.

O wa bẹ wọn pe ki wọn ba awọn eniyan wọn sọrọ ninu igbó pe ki awọn naa wa a gbadun igbe aye alaafia ati imupadabọsipo.

Ọgagun Eyitayọ sọ pe awọn eeyan naa yoo la eto imupadabọsipo kọja ni ibudo ijọba, ki wọn o to darapọ mọ àwọn araalu.

Bakan naa lo sọ pe akitiyan awọn ọmọ ogun ti ko dawọ duro lori ibudo wọn, ìyàn, ìjà, ipenija ilera, ati ìpọ́njú, lo mu wọn yọnda ara wọn.

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú

Ọmọ ẹgbẹ Boko Haram 335, agbalagba obìnrin ati awọn ọmọde àti akẹkọọ Chibok kan, ti apapọ wọn jẹ 746 lo wa lara wọn.

Ọgagun Eyitayo sọ pe wọn yoo samulo ọgbọn Musa Adamu ati Usman Adamu, lati wọle si awọn to ku lára.

Amin iyasọtọ kan

A ti mú afurasí darandaran méjì tó ń da màálù tó kan ọmọ oṣù mẹ́ta pa- Ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NPF

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti sọ pe awọn ti fi ọwọ ofin mu darandaran meji to n da maalu to kan ọmọ oṣu mẹta pa ni Ebrumede ni ijọba ibilẹ Uvwie.

Ọrọ di boo lọ ya n mi nigba ti maalu kan tawọn darandaran meji n mu maalu naa lọ fun onibara ṣadeedee fo ọna mọrosẹ DSC lẹgbẹ ile ẹjọ majisreeti to wa ni Ebrumede.Níbẹ ni maalu ti kọkọ kọlu obinrin kan lati ọwọ ẹyin.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe niṣe ni maalu yii fi iwo rẹ kan ọmọ oṣu mẹta to wa lẹyin iya rẹ.

Wọn ni ori ni maalu ọhun ti fi iwo kan ọmọ ikoko naa eyi to jẹ ki ifarapa rẹ pọ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Ile iwosan Warri Central Hospital ni wọn gbe ọmọ ọhun lọ digba digba, amọ okete ti bo niru.

Awọn dokita gbiyanju agbara wọn lati doola ẹmi ọmọ ikoko yii, ile iwosan yii naa lo dakẹ si.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Maalu ọhun naa ni a gbọ pe o tun jẹ ki baba agbalagba kan ṣeeṣe lẹyin to yabo ile ẹjọ kan nibi t'awọn agbẹjọro ati onibara ti juba ehoro.

Lẹyin awọn iṣẹlẹ yii ni awọn ọlọpaa to wa ni ki Ebrumede mu awọn to n mu maalu naa lọ.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún