Exam malpractice: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arákùnrin tó múra bí obìnrin láti bá ọ̀rẹ́birin rẹ̀ jókòó kọ ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì

Aworan arakunrin to mura bi obinrin

Oríṣun àwòrán, Pulse Senegal

Ọrọ ifẹ, bi adanwo ni.

Arakunrin akẹkọọ fasiti kan ni orileede Senegal ti wọ gau lori pe o mura bi obinrin lati fi ba ọrẹbinrin rẹ joko idanwo ede Gẹẹsi.

Kaakiri oju opo ayelujara ni Senegal lawọn eeyan ti n ṣe alabapin aworan rẹ nibi to ti wọ aṣọ pupa to fi mọ ibori pupa.

Khadim Mboup to jẹ akẹkọọ ọmọ ọdun mejilelogun lawọn agbofinro mu lopin ọsẹ to kọja yi.

Alaye to ṣe nipa iṣẹlẹ yi ni pe ''ifẹ ti mo ni si ọrẹbinrin mi lo mu mi hu iwa yi''

O tẹsiwaju pe ọrẹbinrin rẹ n koju ipenija kikọ idanwọ ede Gẹẹsi naa.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Ni Senegal, ede Faranse ni wọn n sọ ti ede Gẹẹsi si jẹ ede ti ko rọrun fun ọpọ eeyan la ti s tabi kọ.

Asiri Khadim tu lọjọ kẹta to ti n kọ idanwọ nigba tawọn adari idanwo fura si pe imura rẹ yatọ.

Lasiko ti wọn n kọ idanwo ede Gẹẹsi lọjọ Abamẹta ni wọn kesi awọn agbofinro ti wọn si gbe kuro ninu aaye idanwo naa.

Lati ibẹ, awọn agbofinro tọ ọrẹbinrin rẹ lọ ti wn si ri nibi ibugbe awn akẹkọọ to fara pamọ si.

Àkọlé fídíò, Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol

Nigba ti yoo fi di ọjọ Aje wọn gbe lọ si iwaju adajọ lori ẹsun magomagọ idanwo ati lilo orukọ olorukọ bi ti eeyan.

Oun nikan kọ ni o wa nile ẹjọ, ọrẹbinrin rẹ ti wọn jijọ lẹdi apo pọ naa wa nile ẹjọ lọjọ Aje.

Agbẹjọro ijọba sọ pe lỌjọbọ ni wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'