Deji Adenuga : Ìdí tí mo fí jó èèyàn mẹsan mọ ilé

Àkọlé fídíò, Deji Adenuga : Ìdí tí mo fí jó èèyàn mẹsan mọ ilé

Arakunrin ti ọlọpaa ṣe afihan rẹ nitori pe o dana sun mọlẹbi ọrẹbinrin rẹ mẹsan mọle ti salaye ohun to mu hu iru iwa bẹ.

Deji Adenuga nigba ti o n ba akọroyin sọrọ ṣalaye pe nitori pe ọrẹbinrin oun gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira lọwọ ohun ti o si kọ lati fẹ ohun loun ṣe dana sun ile pa awọn mọlẹbi rẹ.

Lọjọ Iṣẹgun ni o sọ ọrọ yi lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa nilu Akure ṣe afihan rẹ.

Bi a ko ba gbagbẹ,Ọwọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo tẹ afunrasi naa ti wọn lo mọ nipa bi ina ṣe jo eeyan mẹsan mọle nilu Akure.

Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ ọdun Ajinde to kọja ni iroyin gbode pe ọwọ tẹ afunrasi naa, Deji Adenuga labẹ afara lẹba ibudoko ni ilu Ijebu Ode.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn oniroyin to wa lagbegbe naa sọ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Femi Joseph ni awọn yoo ṣafihan afunrasi ọ̀hún faraye.

aworan Deji Adenuga

Bi a ko ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun to kọja ni iroyin gbode ladugbo Igbodigo nilu Okitipupa nibi ti awọn mọlẹbi kan ti padanu ẹmi wọn nigba ti eeyan kan sọ ina si ile wọn.

Ohun ti agbẹnusọ ọlọpaa Femi Joseph sọ nigba naa ni pe arakunrin kan Deji Adenuga lo sọ ina si ile ọrẹbinrin rẹ nitori ti o ni oun ko ṣe mọ.

Lati igba naa ni ọlọpaa ti bẹrẹ si ni wa arakunrin yii titi ti ọwọ fi wa tẹ ẹ bayi.

Àkọlé fídíò, Ìbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà