Ondo: Ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat Olubọyo gba ọjọ́ ikú!

Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Ondo ti da ẹjọ iku fun Seidu Adeyemi to pa ọmọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Khadijat Olubọyọ ní ọdun to kọja.
Seidu Adeyemi to jẹ ọrẹkunrin Khadijat Oluboyo ni wọn fẹsun kan wi pe o pa a, ti o si tun riimọle si inu yara rẹ ni Aratusi, Oke-Aro ni Akure, nipinlẹ Ondo.
Khadijat Oluboyo n mura lati jade fasiti ni ile iwe giga fasiti Adekunle Ajasin ni Akungba Akoko ni ipinlẹ Ondo ki o to jade laye










