Kano: Omidan, rìn jáde láago mẹ́jọ alẹ́ ko rẹ́wọ̀n he

Omi tuntun ti rú, ẹja tuntun sì ti wọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Kano báyìí, túntun tó ṣẹlẹ̀ ní pé, ààyè kò si fún ọlọ́mọge láti jáde alẹ.
Yàtọ sí bí ǹkan ṣe rí ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn tí ọmọ obìrin lè wọlé tàbí jáde ní àṣìkò tó bá wù wọn, ní ti ìpínlẹ̀ Kano, ọ̀tọ̀ lọmọ́ sorí o.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹ́gẹ́ bí ofin Sharia tí ìpínlẹ̀ náà gùnlé, wọn ní gbogbo obìnrin tí ọlọ́pàá Hisbah bá ti mú ní ojú pópó pé ó ń dá rìn ní ààgo mẹ́jọ alẹ́ kìí ṣe ọmọ, yóò sì fí ojú ba àgọ́ ọlọ́pàá.
BBC sàbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ Hisbah lọ́jọ́rú láti rí àwọn ọmọbinrin kan tó ti ṣẹ̀ sí òfin yìí ní ọjọ́ ìṣẹ́gún, tí wọn sì sun ọgba Hisbah mójú.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọpaa Hisbah ṣe sọ, oní nààbì ní àwọn ọmọbinrin yìí, tí wọn sì ń wa àwọn oníbara nínú iṣẹ́ wọn, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin yìí ló sọ pe, ìdíkan tàbí òmíràn ló gbé àwọn jáde kúrò nílé ní àsìkò ti wọn mú àwọn.
Agbẹnusọ fún àjọ náà, Mallam Adamu Yahaya tó ba BBC sọ̀rọ́ sàlàyé pé, ó jẹ́ ọkan lára ojúṣẹ́ àwọn láti máa mú àwọn ọmọbinrin tó bá ń rìnrìn àrè kákìri ìlú, ó si ṣeéṣe kí wọn jẹ́ aṣẹ́wo.

Ó ní '' ojoojúmọ ní àwọn ọkùnrin máa ń jáde láti da ǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn yìí, tí a bá mú wọn, ti a sì rii dájú pé wọn kìí ṣe àṣẹ́wo, a ó fi wọn sílẹ̀ láti máa ba tiwọn lọ.
Ọkan nínú àwọn ọmọbinrin tí wọn mú tó wà níbẹ̀ sàlàyé fún BBC pé, òun jáde nílé láti lọ kí ọ̀rẹ́ oun ní ǹkan bíi ààgo mẹ́sàn alẹ́ ní àwọn Hisbah ba mú òun sínú motò wọn.
Wo aworan igbeyawo ọmọ gomina Ọyọ ati ti Kano

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna
Ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ, Idris Abiọla, Ajimọbi ti gbe ọmọ gomina ipinlẹ Kano, Fatima Ganduje, niyawo lọjọ Abameta.
Ọlọkan-ojọkan alejọ pataki ni wọn kalẹ si ipinlẹ Kano nitori igbeyawo naa.
Sugbọn awọn ọmọ Naijiria kan koro oju si bi Aarẹ Muhammadu Buhari ti lọ sibi igbeyawo naa ti ko si lọ si ilu Dapbchi ti wọn ti ji awọn akẹkọbirin gbe.

Oríṣun àwòrán, @BuhariSallau

Oríṣun àwòrán, @Dawisu

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Oríṣun àwòrán, GovKaduna

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki













