Man sets girlfriend ablaze: Saka dáná sun 'ààlè' rẹ̀ tọmọ-tọmọ n'Ibadan, òun nàá tún jóná kú

Oríṣun àwòrán, other
Iroyin kan to tẹ wa lọwọ ni pe ọkunrin kan, Ahmed Saka, ti dana sun ara rẹ ati olulufẹ rẹ nigba kan, Mutiat Oladele ati ọmọ meji nilu Ibadan.
Iroyin sọ pe niṣe ni Saka lọ ọ dana sun ile Arabinrin Mutiat, to jẹ aale rẹ, nitori pe obinrin naa fi opin si ọrọ ifẹ to wa laarin wọn.
A gbọ pe obinrin naa ati meji ninu ọmọ rẹ lo ku nitori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni iroyin sọ pe ọkunrin naa pada ku, ti awọn ọmọ Mutiat mẹtayooku si di eero ileewosan nitori ifarapa ti wọn ni.
Alẹ Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Shogoye, ni Idi-Arẹrẹ, nilu Ibadan.
Akọroyin BBC nilu Ibadan sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Lara iroyin to n lọ ni pe Saka ati Mutiat n yan ara wọn lale ṣaaju iṣẹlẹ yii.
Amọ, Mutiat sọ pe oun ko ṣe mọ, eyi to mi ki Saka o dun kooko pe oun yoo pa ara oun, yoo si tun pa Mutiat.
Gbogbo igbiyanju wa lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi sọrọ lori iṣẹlẹ naa titi di asiko ti a jabọ iroyin yii, ni ko so eso rere.












