Bobrisky: Mo ti parí iṣẹ́ abẹ ìdí mi, oúnjẹ ti ṣetán o, ẹ wá jẹun

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Gbajumọ ọkunrin to maa n mura bi obinrin, Okuneye Idris Olarenwaju ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Bobrisky ti fi aworan rẹ lede lẹyin iṣẹ abẹ idi to ṣe.

Ṣaaju ni Bobrisky ti kọkọ kede pe oun yoo ṣe iṣẹ abẹ idi naa ki ibadi oun le gbe pẹli si daadaa bii ti obinrin.

Ko pẹ lẹyin ikede naa to fi aworan bi iṣẹ abẹ naa ṣe lọ lede, nibi to ti ṣalaye pe oun wa ninu irora nitori iṣẹ abẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'

Wayi o, ọkunrin bi obinrin naa ti wa kede pe iṣẹ abẹ ọhun ti pari, ati pe eku ke bi eku, ẹyẹ si ke bi ẹyẹ lori iṣẹ abẹ naa.

Lasiko to n fi aworan rẹ tuntu lede loju opo Instagram ati Facebook rẹ, Bobrisky wọ aṣọ penpele 'Bikini' to si sọ pe "Ounjẹ ti ṣetan o, ta lo fẹ jẹun."

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Ẹwẹ, pupọ awọn eeyan to n tẹlẹ lori ayelujara lo n bu ẹnu atẹ lu pe irọ lo n pa, ati pe ko ṣiṣẹ abẹ kankan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mii n ki ni mẹsan an mẹwaa lori iṣẹ abẹ naa, awọn miran n sọ pe ẹrọ atun aworan ṣe, Photoshop, lo fi ṣe aworan idi tuntun to fi sori ayelujara.

Ọkan lara awọn eeyan naa ni lẹyin ti oun wo aworan naa finifini, oun le fide rẹ mulẹ pe irọ lo n pa nitori ẹrọ Photoshop lo fi ṣe afikun ibadi ọhun.

Ẹwẹ, pẹlu bi awọn eeyan ṣe n bu Bobrisky to lori iṣẹ abẹ idi naa to, ko fun ẹnikẹni ninu wọn lesi.

Okuneye Idris Olarenwaju di ọkan gboogi lara awọn ilumọọka laarin awọn ọdọ ni Naijiria lẹyin to pa orukọ da si Bobrisky to si bẹrẹ si n mura bii obinrin.

Bo tilẹ jẹ pe ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abo lodi si ofin ni Naijiria, ko tii si ẹni to tii fidi rẹ mulẹ pe Bobrisky n ba ọkunrin bii tirẹ ni ibalopọ bo tilẹ jẹ o maa n mura bi obinrin.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation