TB Joshua: Kí ni ìdí tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn yìí ṣe kọ̀ láti yọjú síbi ètò ìsìnkú TB Joshua?

Oríṣun àwòrán, Facebook
Lẹyin iku wolii Temitope BalogunJoshua, ti ọpọ eeyan mọ si TB Joshua ni ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ.
Lara awọn eeyan naa ni awọn gomina, Aarẹ, minisita, awọn oṣere atawọn alẹnulọrọ mii lawujọ.
Ṣugbọn lọjọ ti TB Joshua wọ kaa ilẹ sun ninu ijọ rẹ, Synagogue Church of All Nations, SCOAN, ọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun bii tirẹ ti awọn eeyan n reti nibi ayẹyẹ isinku ọhun ni ko yọju rara.
TB Joshua jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta lẹyin to dari isin kan tan ni ile ijọsin rẹ lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ti a wa yii.
Ṣaaju ni ijọ SCOAN ti kọkọ kede pe eto isinku naa yoo waye laarin ọjọ karun un si ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2021, nibi ti wọn ti n reti obitibiti ero.
Ẹwẹ, iyalẹnu nla lo jẹ fun ọpọ awọn bi wọn ko ṣe ri awọn iranṣẹ Ọlọrun nla-nla miran nibi ayẹyẹ isinku ọhun.
Gẹgẹ bii ọrọ ti awọn eeya n sọ nibi eto isinku naa, lara awọn iranṣẹ Ọlọrun jankan-jankan ti wọn ko ri ni pasitọ agba ijọ RCCG, Enoch Adeboye, pasitọ Sam Adeyemi ti ijọ Daystar, adari agba ijọ Living Faith, Biṣọọbu David Oyedepo.
Ko tan sibẹ, awọn ojiṣẹ Ọlọrun miran ti awọn eeyan ko tun ri ni adari ijọ Deeper Life, W.F. Kumuyi, Paul Enenche ti ijọ Dunamis ati Lazarus Mouka ti ijọ The Lord's Choosen.
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Yomi Fabiyi sọ̀rọ̀ sókè lóri bí TAMPAN ṣe gbé igi le lẹ́yìn
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Bobrisky fi àwòrán tuntun léde lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
Bakan naa lawọn eeyan tun reti awọn pastọ mii bii Chris Okotie ti Household of God Church International Ministries, Tunde Bakare ti ijọ Citadel Global Community Church ati pasitọ Matthew Ashimolowo to jẹ adari ijọ Kingsway International Christian Centre.
Ọpọ eeyan lo ti n woye idi ti awọn ojiṣẹ Ọlọrun wọnyi atawọn miran to lamilaaka ni Najiria ko ṣe yọju, ṣugbọn iroyin ni lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa ran awọn aṣoju wọn lọ sibi ayẹyẹ ikẹyin ọhun.
Sibẹ, awọn eeyan jankan mii to peju sibi eto isinku naa ni Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo; aṣoju gomina ipinlẹ Eko, Olarewaju Elegushi; Aarọ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, aya Ooni Ile Ife, Olori Naomi Adeyeye; minisita tẹlẹri fun eto irinna ọkọ ofurufu, Femi Fani-kayode ati Oloye Bibopere Ajube.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ati ọpọ ojiṣẹ Ọlọrun ni Naijiria ni ko sọ ọrọ kankan lẹyin iku oloogbe ọhun.
Ṣugbọn CAN fi atẹjade kan lede lati ba ẹbi oloogbe naa kẹdun lẹyin nnkan bi ọjọ mẹta lẹyin iku rẹ.
- "Kò sí Pásítọ̀ tó ṣiṣẹ́ ìyanu, tó lé ẹ̀mí èṣù jáde bíi TB Joshua"
- "Odeeshi"! Baba Ijesha, Yomi Fabiyi àti gbogbo àwọn tó fẹ́ pa mi, èèyàn lásán niyín o - Iyabo Ojo
- Ẹ wo bí ìṣìnkú TB Joshua ṣe ńlọ ní Arigidi Àkókó lónìí tí yóò wọlẹ̀ sùn!
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
Ẹkun sọ bí wọ́n ṣe gbé Wòlíì TB Joshua bọ ilẹ̀ nínú gbọ̀ngan ìjọ Synagogue

Oríṣun àwòrán, Emmanuel TV
Mọlẹbi Wolii TB Joshua ati gbogbo ijọ Synagogue lagbaye ti fi eeru fun eeru, wọn si ti fi erupẹ fun erupẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe isin ikẹyin fun oloogbe naa ninu ij synagogu to wa nipinlẹ Eko, wọn ti gbe e sinu ile ikẹyin rẹ laye bayii.
Awọn eniyan jankanjankan ti n de si ibi isinku gbajugbaja Woli to jade laye, TB Joshua ni ẹni mẹtadinlọgọta.
Lara awọn to ti de si be ni Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu to fi mọ gomina ipinlẹ Ogun, Abiodun.
Bakan naa ni awọn eniyan jankanjankan lati awọn ilẹ ijọsin Kristẹni kaakiri agbaye lo ti wa nibẹ.
Lara awọn eekan to ti wa nibi eto isinku naa ree


Oríṣun àwòrán, Olori Naomi
Òní ní Wolìí TB Joshua yóò wọ káà ilẹ̀ sùn, bí ètò ṣe ńlọ rèé...
Oni ni ọjọ ti ile ijọsin Synagogue of All Nations yoo sin oku oludasilẹ wọn, TB Joshua.
Ayika ile ijọsin naa ni wọn yoo sin i si ni owurọ Ọjọ Kẹsan, Osu Keje, ọdun 2021.
Lẹyin osu kan ti TB Joshua papoda ni wọn ṣeṣẹ fẹ eto isinku rẹ.
Ijọ SCOAN fi atẹjade sita ni were to ku wi pe ọṣẹ kan ni wọn yoo fi ṣe eto isinku rẹ, lati ọjọ karun un , osu keje, pẹlu titan abẹla yika ilẹ adura rẹ, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun marun un si pejọ sibẹ.
Ni Ọjọ Tuesday ni Ọjọ iwuri ti awọn eniyan pejọ pọ lati sọ ohun ti wọn mọ nipa igbe aye TB Joshua.

Oríṣun àwòrán, TB Joshua
Ni Ọjọ yii ni awọn eniyan jankan jankan ni awujọ pejọ to fi mọ awọn oṣere to lamilaaka lorilẹede Naijiria jade lati wa sọ ọrọ iwuri nipa rẹ.
Ayajọ asalẹ orin waye ni Ọjọru, ti awọn olorin to fi mọ Timi Dakolo, Shasha Malley lati orilẹede Ghana naa ko gbẹyin ni bẹ.
Awọn eniyan pejọ ni Ọjọbọ lati wo oku rẹ nibi ti wọn tẹ si ninu ile ijọsin, ti ọpọlọpọ eniyan si n ṣe idarọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Emmanuel TV
Ọpọlọpọ lo mọ TB Joshua nitori awn iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu ti o ma n waye ni ile ijọsin rẹ, eleyii ti o si si sọ ọ da ilumọọka kaakiri agbaye.
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- Olórí Eléégún, Ìmáàmù àti èèyàn márùn-ún míì dèrò àtìmọ́lé l‘Osogbo
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
Bi o tilẹ jẹpe ko si ẹnikẹni to mọ patọ ohun to ṣekupa, lẹyin to waasu tan ni ile ijọsin ni o wọle lọ ti wọn si ba ni ori ijoko to ti dake si.














