TB Joshua burial: Àwọn obìnrin Akoko ní kò sí ọmọbíbí ilẹ̀ náà tó tọ́jú àwọn bíí olóògbé

Oríṣun àwòrán, Tb joshua ministries/facebook
Bi eto isinku Wolii Temitope Balogun Joshua ṣe ti bẹrẹ lati ọjọ Aje, awọn Iyalaje ati Iyalọja ni ilẹ Akoko nipinlẹ Ondo ti pinnu lati ti gbogbo awọn ọja pa ni ọjọ Ẹti.
Ọjọ Ẹti gan-an ni wọn yoo sin oku oloogbe.
Atẹjade lati ọdọ Iyalaje ti ilu Ikarẹ-Akoko, Alhaja Risikat Mohammed sọ pe awọn ṣe bẹẹ lati bu ọla fun ọmọ wọn to ku.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- Irọ́ pátápátá ni pé mo gba 50milion nairà látí ṣe alátakò Sunday Igboho - Olubadan
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun
- Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ba orúkọ mi jẹ́ tórí sabuké NYSC mi, mò ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò - Kemi Adeosun
O ni ko si ifarada to tobi ju lati fi yẹ ẹ si fun ifẹ, aanu ati oore to ṣe fun awọn eniyan rẹ nigba to wa laye.
O ni eyi yoo tun fun wọn ni anfaani lati wo bi eto isinku naa ba ṣe n lọ lori ẹrọ amohunmaworan ijọ Synagogue, Emmanuel TV.
Ẹlomii, to jẹ olori fun gbogbo awọn obinrin to jẹ oye ni ilẹ Akoko, Oloye Margaret Ebun Oladunni sọ pe ọsẹ ọfọ ni ọsẹ yii jẹ fun ilẹ Akoko.
O ni ko si ọmọ bibi ilẹ naa to ti ku tabi to wa laye, to ṣe itọju awọn eniyan rẹ bi TB Joshua.















