TB Joshua: Wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí òkú wòlíì yọ sí òṣèrébìnrin, Jaiye Kuti

Jaiye Kuti ati TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries and jayeola_monje/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣerebinrin, Jaiye Kuti sọ iriri rẹ nipa bi òkú Woli Temitope Joshua ṣe yọ si.

Oṣerebinrin, Jaiye Kuti ni oku oloogbe, Woli Temitope Balogun Joshua, to jẹ oludasilẹ ile ijọsin Synagogue Church of All Nations, yọ si oun lẹyin iku rẹ.

Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Kuti sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe TB Joshua yọ si oun, bo tilẹ jẹ pe oun ko ri loju koroju ri nigba to wa laye.

Àkọlé fídíò, Ẹ pàdé olórin Fuji alhaji Besco tó jọ Ayinde Barrister to tún ń kọrin gẹ́lẹ́ bíi tirẹ̀

Ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa ni Woli naa jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.

Oṣerebinrin naa sọ pe nise ni ori oun dide jan-in lasiko ti oku TB Joshua yọ si oun, ti oun si ri to rọra kọja lọ jẹjẹ.

Ọrọ ti Jaiye Kuti sọ

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje/Instagram

"Mi o ri ri lojukoroju, sugbọn oku rẹ yọ si mi nigba to ku.

Emi nikan ni mo wa ninu yara mi ni ilu Offa, ti mo deede ri to kọja. Ori mi dide. Nkankan to dara wa nipa ẹ̀mí naa."

"Alaini ni Kristi, sugbọn o bọ́ awọn eniyan, o si n tọju gbogbo eeyan. Bẹẹ ni ìwọTB Joshua naa ṣe fun ọpọlọpọ.

Àkọlé fídíò, Ẹ pàdé olórin Fuji alhaji Besco tó jọ Ayinde Barrister to tún ń kọrin gẹ́lẹ́ bíi tirẹ̀
Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are
Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

Eeyan meji ni mo mọ to fi aye wọn fun Jesu ni tootọ nipasẹ rẹ̀."

Jaiye Kuti ni oun gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Woli T. B Joshua si afẹfẹ rere.

Bakan naa, nigba to n fesi si awọn ọrọ ti awọn ololufẹ rẹ kọ si abẹ awọn nkan to sọ nípa T. B Joshua, paapaa nipa nkan ti awọn eniyan sọ nipa oloogbe nigba aye rẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Jaiye Kuti sọ pe awọn erokero naa ko yọ oun silẹ. O ni oun naa gbagbọ bi awọn eeyan ṣe sọ pe Joshua kii ṣe iranṣẹ Ọlọrun tootọ.

"Gbogbo wa la jẹbi awọn ọrọ naa nípa rẹ, nitori pe a ko ri aridaju nipa iru eniyan to jẹ."

Oserebinrin naa wa n beere pe ta ni eeyan Ọlọrun gan bikose ẹni to se awọn ofin rẹ, to si jẹ pe awọn ojisẹ Ọlọrun nkan wa, to jẹ pe owo ni wọn n wa.

"Wọn ko ni fi ọrọ Ọlọrun gan bọ wa debi pe a mọ ẹni ti Ọlọrun jẹ, okoowo ni wọn n fi ẹsin Kristiẹni se.

Ni Italy, wọn maa fun wa lowo tori pe a wa sile ijọsin, wọn yoo fun wa lowo lati wa sin Ọlọrun ni amọ nibi yii, ohun gbogbo ta ni la fi n sin awọn ojisẹ Ọlọrun."

Àkọlé fídíò, TB Joshua: Ṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń wa ẹkún mu torí ikú òjijì tó pa wòlíì

O fikun pe ọpọ eeyan ni ko mọ ofin orilẹede yii amọ wọn le ka bibeli lori lati ibẹrẹ de opin.

O wa kede pe wọn kan n fi ẹsin tu wa jẹ lasan ni, to si jẹ pe ọtẹ ati tẹmbẹlẹkun lo kun inu ọpọ eeyan to n fi ara rẹ we Kristi.