Nigeria debt with China: ÌJọba Naijiria ti yá $2b lọ́wọ́ China láàrín ọdún mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, BBC Hausa
Iye owo ti ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti ya lọwọ orilẹ-ede China lati ọdun 2015 si asiko yii ti le ni biliọnu meji dọla.
Ẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ gbese ni Naijiria, DMO, lo kede bẹ ninu atẹjade kan.
Atẹjade naa fi han pe iye owo ti Naijiria ti ya lọwọ China ki Aarẹ Buhari to gori alefa jẹ $2.38b.
Ṣugbọn nigba ti yo fi di oṣu kẹta ọdun 2021, iye owo ti Naijiria ti jẹ ti le ni nnkan bii $3.4b.
Ṣaaju ni ileeṣẹ iwe iroyin abẹle kan ti kọkọ jabọ pe nnkan bii ida meji abọ ni iye owo ti Naijiria n ya lọwọ China lọdọdun fi n goke si i, ati pe o ṣeeṣe ko tun pọ ju bẹẹ lọ ko to di ogun ọdun si asiko yii.
Pupọ ninu owo ti ijọba Naijiria n ya lọwọ China ni wọn n na lori awọn akanṣẹ iṣẹ bii kikọ oju ọna ọkọ reluwe lọna ati mu idagbasoke ba ẹka irinajo ni Naijiria.
Lara awọn akanṣẹ iṣẹ ti ijọba Buhari fi gbese China ṣe ni ọna oju irin Kaduna, to fi mọ ti ilu Abuja, ipinlẹ Eko, ati Kaduna si Kano.
Pupọ awọn ọmọ Naijiri lo ti n fi erongba wọn lede pe o ṣeeṣe ki ijọba China gba iṣakoso awọn dukia ijọba kan ti Naijiria ba kọ lati da awọn owo naa pada.
Ṣugbọn minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi ti sọ pe ko ṣeeṣe ki China gbẹsẹle awọn ohun ini Naijiria niwọn igba ti awọn ba n san gbese ọhun diẹdiẹ.
Bo tilẹ jẹ minisita naa fi ọkan awọn araalu balẹ lori gbe ọhun, ọpọ ọmọ Naijiria lo n ṣo pe awọn atawọn ọmọ-ọmọ wọn, titi de irandiran ni yoo san gbese naa.
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Tope Alabi fẹ́ tọ́ Olórin "Oniduro mi e ṣe" sọ́nà, bí ọ̀rọ̀ ṣe laná nìyìí
- Wo ohun tí Dele Momodu sọ nípa TB Joshua lẹ́yìn ikú rẹ̀














