Michael Packard: Ọkùnrin kan tó bọ́ sẹnu ẹja àbùùbùtán nínú òkun sọ bí orí ṣe ko yọ

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Michael Packard ti salaye bo se ba ara rẹ lẹnu ẹja abuubutan fun bii aabọ isẹju ni Massachusetts, lorilẹede Amẹrika.
Ẹja abuubutan naa, ti wọn n pe ni Whale, lo pada pọ ọkunrin naa jade lẹnu rẹ, to si jẹ pe orunkun nikan ni ọkunrin naa Packard, fi sese.
Bi o tilẹ jẹ pe iyawo rẹ ti n bẹbẹ pe ki Packard wa isẹ oojọ miran se, amọ o ni oun ko ni lori ero lati fi isẹ bibẹ sinu omi Cape Pod silẹ, eyi to ti n se fun ogoji ọdun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ ìlú tó sọ̀rọ̀ tako èrò Tope Alabi nípa orin "Oniduro Mi"
- Wo oríadé méje tí ẹ̀ṣùn ìwà ìjínigbé ṣí mọ́ lórí
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
Ẹja abuubutan yii si lo maa n dagba, ti yoo si gun to mita mẹẹdogun, tii se aadọta ẹsẹ bata.
Bakan naa lo tun maa n tobi to tọọnu mẹrindinlogoji, gẹgẹ bi ajọ to wa fun ẹdawo imọ nipa ẹranko igbẹ ti wi, awọn ẹja yii to ẹgbẹrun lọna ọgọta lagbaye.
Ọgbẹni Packard, tii se ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, salaye fun awọn akọroyin pe oun ati awọn akẹẹgbẹ oun gbe ọkọ oju omi awọn ni aarọ ọjọ Ẹti naa nitori oju ọjọ to dara.
O ni awọn tun ni anfaani lati ri ilẹ omi to to ẹsẹ bata ogun.
Packard salaye pe nigba ti oun danu latinu ọkọ oju omi naa, ni oun gbọ ti nnkan lanu gbe oun sẹnu, ti ohun gbogbo si dudu wa loju oun.
"Haa, Ọlọrun o, mo ti wa lẹnu ẹja, to si n gbiyanju lati gbe mi mi, O tan bayii, iku lo ku fun mi bayii."
Se ni Packard bẹrẹ si ni ronu nipa iyawo rẹ ati ọmọ rẹ meji, ọkan jẹ ẹmọ ọdun mẹẹdogun nigba ti ekeji jẹ ọmọ ọdun mejila.
Amọ lojiji, lo pada sori ilẹ pada, to si jade ni ahamọ, to si n mi ori rẹ lugbe-lugbe.



















