NAF bombs wedding: Kàyéfì, Àwa ò ṣèèsì ju àdó olóró sáàrín àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó o!

Kàyéfì, ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèsì ju àdó olóró sáàrín àwọn tí ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó.

Oríṣun àwòrán, Airforce

Ọkọ̀ òfurufú àwọn ọmọogun òfurufú Nàìjíríà ju àdó olóró si aarín àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó ní abúlé kan ní ìpínlẹ̀ Niger.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, àwọn jándùkú agbésùmọ̀mí ni wọ́n ń gbìyànjú láti ju àdó olóró náà lù lágbègbè náà láìmọ̀ pé àwọn ará ìlú ni.

" A rí báàúù kékeré tó n ju adó olóró láti ọ̀nà jínjiń ti àwọn jàndukú tó wà níbl sì n sá kíjo, sùgban lójìji ni ọ̀kan nínú adó olóró náà lọ yà sí ibi ti àwọn kan ti n ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó nílùú Argida.

Àkọlé fídíò, 'Walahi kìí ṣe irọ́ pé Fulani ń dá àwọn èèyàn lọ́nà nílẹ̀ Yorùbá, ìrírí mi rèé'

" Àwọn ará ìlú méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn, a tún ri gba pé àwọn alejò mííràn níbi ayẹyẹ náà farapa yánayàna.

Ní inú oṣù kẹrin ọmọogun ojú òfurufú náà pa àwọn ọmọogun kan ti wan ni àwọn ṣe àṣìṣé.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọogun nínú fọ́ran kan ti iwé ìròyìn Gazette gbé jáde ni a ti ri ọ̀kanm nínú awọn tórí kóyọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí bẹ̀bẹ̀ fún ìránlọ́wọ́.

Àaọn ọmọogun sọ poé, ibi ti ọkọ ìjà àwọn ọmọogun ojú ofurufu nàka si fún àwọn ni àwọn ju àdó olóró sí.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ogun ofurufu ti fi atẹjade sita pe irọ nla ni ọrọ naa gẹgẹ bi iwe iroyin The Nations ṣe sọ pe awọn ko ju ado oloro sibi ayẹyẹ kankan.