Igboho and June 12 protests: Sunday Igboho kan sárá sáwọn ọmọ Yorùbá tó wọ́de lọ́jọ́ Sátidé

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, other

Sunday Igboho ti kan sara sawọn ọmọ Yoruba to jade wọde kaakiri gbogbo agbaye lọjọ Satide fun iwọde June 12 pe wọn ku ifọmọniyan ṣe.

Oloye Sunday Igboho to ṣalaye ninu fidio kan to fi sita lori ayelujara pe inu oun dun daadaa fun bi awọn eeyan ṣe jade fun iwọde naa ṣalaye pe o fihan pe waasimi 'Yoruba Nation' to n lewaju fun ti sunmọle.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ero, paapaajulọ awọn ololufẹ Sunday Igboho ni wọn reti pe yoo jade lati lewaju awọn iwọde kọọkan lọjọ Satide, ṣugbọn Sunday Igboho ko si ni eyikeyi awọn iwọde to waye naa kaakiri awọn ipinlẹ Yoruba.

Amọṣa o, Sunday Igboho ko sọ idi ti ko fi si ni eyikeyi awọn iwọde naa.