Lizzy Anjorin: New York, Atlanta, Chicago àtàwọn ìlú méje míràn l'Ámẹ́ríkà yóò gbàlejò ayẹyẹ ìkómọ ọmọ Lizzy Anjorin

Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy Anjorin

Ẹyin eeyan wa, tẹẹ ba ro wipe ẹ ti wo gẹlẹdẹ opin iran lori ọmọ ti gbajumọ oṣere, Lizzy Anjọrin ati ọkọ rẹ ṣẹṣẹ bii, ẹ gbayi yẹwo, tuntun ni o.

Laipẹ yii, Lizzy Anjọrin ati ọkọ rẹ ki ọmọ wọn akọbi kaabọ ni ilu Florida, lorilẹede Amẹrika.

Nibayii, Lizzy ti fọn fọto ọmọ rẹ naa sori ayelujara bayii pẹlu orukọ rẹ.

Bakan naa ni Lizzy Anjọrin tun tu u sita pe eto ayẹyẹ isọmọlorukọ fun ọmọ oun naa yoo waye lọpọlọpọ awọn ilu nlanla lorilẹede Amẹrika.

O ni apejẹ alaṣọ funfun ni wọn yoo fi isọmọlorukọ ọmọ awọn ṣe ni ilu mẹwaa ọtọọtọ.

O ni ilu New York ni yoo ti bẹrẹ ni ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2021, yoo yi kan awọn ilu bii Dallas, Atlanta ati Indiana laarin ọjọ kọkanla, ikejidinlogun ati ikarundinlọgbọn oṣu keje naa.

Nigbati Maryland, Houston Texas ati North Carolina yoo waye ọjọ kini, ikẹjọ ati ikarundinlogun oṣu kẹjọ.

Ọjọ kejilelogun ati ikọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ kan naa ni yoo kan awọn ti Minnesota ati California ki wọn to fi adagba rẹ rọ ilu Chicago loṣu kẹsan ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò