UFC 263 results: Israel Adesanya fàgbà han Vettori lẹ́ẹ̀kejì nínú ìjàkadì UFC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajijakadi ọmọ Naijiria, Israel Adesanya ti jẹwọ ara rẹ bii ọmọ Akin lẹyin to fọ Marvin Vettori lẹnu ninu ija UFC 263 to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ni gbagede Gila River.
Aṣeyọri naa ti mu ki Adesanya si wa lori itẹ gẹgẹ bii ajijakadi to lamilaaka julọ ni ipele "middleweight" ni UFC.
Lẹyin ti ijakadi naa de ipele karun ni awọn to n dari rẹ sọ pe o to gẹ, ti wọn si kede maaki 50-45, 50-45, 50-45 gẹgẹ bii esi ijakadi ọhun, eyii fi han pe Adesanya lo gbegba oroke.
Eyii ni igba keji ti Adesanya yoo fagba han Vettori ninu idije UFC.
Igba akọkọ ti awọn mejeji kọkọ wọya ija ni oṣu Kẹrin ọdun 2018, eyii to jẹ ijakadi keji ti Asdesanya yoo kopa ninu rẹ ni UFC.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe Vittori halẹ ni abala akọkọ ijakadi ọhun, ṣugbọn Adesanya fagba han an pẹlu ọpọlọpọ ẹṣẹ ati ikuku.
Adesanya lo bori ija ọhun bo tilẹ jẹ pe Vittori ti kọkọ n lẹnu ṣaaju pe oun yoo fi ọpalamba ija jẹ Adesanya.
Aṣeyọsri yii ni igba kẹta ti Adesanya yoo ṣe jaweolubori gẹgẹ bii ajijakadi to milẹ julọ ni ipele middlewweight ni UFC.












