Israel Adesanya: Romero yóò jìyà bí mo bá gbá a mú

Romero ati Isreal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ǸJẹ́ ẹ̀yín mọ Adesanya tó ní òun yóò dá bàntẹ́ ìyà fún Romero?

Sebi wọ́n ni ti òògun ẹni ba dáni loju, a maa fi n gbári ni, ọmọ yoruba míràn tún rèé nínú ere idara abẹsẹ kù bi ojo.

Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ ṣe ri bi Isreal Adesanya ṣe n sele ri pe ajẹku iya ni Yoel Romero yoo jẹ ninu idájukọ ti yóò wáye lola ode yiì.

Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ.

Àkọlé fídíò, Obasanjọ: Ọbasanjọ ní òhun yóò fi ìyókù ayé òun san oore Ọlọrun ni
Àkọlé fídíò, Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò

Abẹsẹkubiojo Kiwi Middleweight fun UFC yoo koju Romero nínú ija oni pele marun ni Las Vegas ní ọla ode yìi, eyi ti yoo jẹ ijà akọkọ láti igba ti o ti doju Robert Whittaker boleẹ̀ninu oṣu kẹwàá ọdun to kọja, eyi túnmọ si pe ìpo Middleweight náà tọ si ti o ba na Romero

Romero máà n fi ara rẹ han bi ẹni to le koko ti ko si si ẹni to le bori rẹ lati igba to ti yan iṣẹ́ náà láàyò.

Ẹni ọdun méjilelogoji ọmọ Cuba oun kuna ri ni ẹ̀ẹ̀mẹta láti ọjọ to ti n dije, ẹ̀ẹ̀mta náà si rèé, igbimọ jòkó ni láti mọ ẹni ti wọ́n yoo gbe ade fún.

Gbogbo èniyan lo mọ Romero fún bi o ṣe maa n ja ija tirẹ pẹlu ìwà ipa àti wáranwanran sise

"Kìí ṣe ẹni ti ẹnikẹni máà n fẹ́ bá ja" Adesanya lo sọ eyi.

" Ìdí? ìdí ni pe mo ti ri ti wọ́n ti lùú, mo ri ti wọ́n daa dúro, mo ti ri bi ẹjẹ̀ ṣe bòo', mo ri nibi to ti n sunkún, ẹmi gan náà yóò mu sunkun, èèyan ẹlẹran ara bi ti gbogbo aye ni.

" mo fẹ́ lùú ni marun si odo, mo fẹ wẹ ki n yan kankan, ki n náà ni alubolẹ, bo ba le ku ko kú, ìyẹn kii ṣe isoro temi"

Adesanya pe Romero nija láti báa ja, nigbati àwọn alaṣẹ fori ko wọ́n ko fààye gba Paulo Coasta lati koju rẹ bákan náà nitori o farapa ni ọdun to kọja.

Tani Isreal Adesanya?

Isreal Mobolaji Temitayo, Odunayo, Oluwafemi Owolabi, Adesanya jẹ́ ọmọ Naijiria ti o n gbe Newzealand, ni Auckland,

O jẹ́ abẹsẹku bi ojo, lọ́wọ́lọ́wọ́ àbẹ́ àdéhun Utimate Fighting Championship ló wà to si jẹ Middleweight Champions.

A bi ni ọdun 1989 ni ìpínlẹ̀ Eko ni Naijiria, o si ni ẹgbọn ati aburo mẹrin

Femi ni orukọ baba rẹ osi jẹ olusiro owo nígba ti iya rẹ Taiwo jẹ Nọoṣi, Isreal lo si ile iwe Chrisland School ni Opebi to si n kọ ẹkọ Takwando to ba kuro ni ile iwe, ọdun 2001 lo lọ si orilẹ̀-èdè Ghana pẹlu ẹbi rẹ ki wọ́n to lọ si Newzealand.

O yà si idi iṣẹ́ to yàn láàyo nítori bi awọn akẹgbẹ rẹ se máà n dẹyẹ si ni kékére, o ti ja ni Honkong, Australia, àti China o si ti de ipele ti o gba 11-0

O wọ adéhun pẹ̀lú Utimate Fighting Championship ni ọdun 2017.