Isreal Adesanya fàgbàhàn Kelvin Gastelum ni Atlanta

Isreal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, A ju ra wa lọ , ijakadi nikan kọ

Ninu idije oni ipele marun un ni Isreal Adesanya ti gbo ewuro soju Kelvin Gastelum.

Agbegbe Farm Arena ni Atlanta ni Georgia lo ti fagbahan Kelvin nibi idije UFC 236.

Opọ eyan lo gboriyin fun Isreal ti a bi ni Naijiria lori awọn ọna ifakayọ rẹ.

Kete ti Isreal jawe olubori yii ni o ti sun soke di 17-0 ninu akọsilẹ ija rẹ.

O gboriyin fun Kelvin ti wọn jọ gbe ina woju ara wọn pé akin ni ninu ija.

O ni: Kelvin fi ara re han ni ọmọ ogun ilẹ Mexico to jẹ akinkanju lẹnu ija ni bẹẹ mo ti pinnu lati ibẹrẹ pe ohun to ba gba ni mo maa fun un.

Ibẹrẹ kii ṣe oniṣẹ ni ọrọ ija naa jasi nitori pe Gastelum lo kọkọ n din dundun iya fun Isreal ki o to fi agbara kun agbara.

Àkọlé fídíò, Bí o ṣe lè fí òǹkà, ọ̀mọ̀ ìka tàbí ìkúùkù wọn oúnjẹ́

Isreal to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn naa ba di agbo to fẹyin rin to lọ mu agbara wa, lo jẹwọ ọmọ ọkọ fun Kelvin nigba to ṣina fun un.

Nigba ti o fi maa di ipari akoko ija naa ni gbogbo awọn to n woran ni Atlanta ti bẹrẹ si ni kigbe orukọ ọmọ Naijiria olugbe New Zealand naa.

Àkọlé fídíò, JAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe
isreal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Isreal Adesanya fàgbàhàn Kelvin Gastelum ni Atlanta

Adesanya ba gba ogo pẹlu 48-46 ni eyi ti yoo jẹ ko tun lọ koju Robert Whittaker ọmọ ilẹ Australia nipele idije ẹṣẹ kikan to tẹle eyi.

Ni ibẹrẹ ọdun yii lo yẹ ki Whittaker koju Kelvin Gastelum ṣugbọn eyi ko waye lataari iṣẹ abẹ ti o ṣe.

Iroyin to gbode ni pe yoo pada soju ija laarin oṣu kẹfa si ikẹjọ ọdun yii.

Bi ori ba le jẹ ki Adesanya fagba han Whittaker, a jẹ pe o ti gba ami ẹyẹ abẹṣẹ-kubi-ojo ni yẹn.

Àkọlé fídíò, Ọ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ