Bring back our girls: Obi àwọn ọmọ Chibok 34 ló kú ní ọdún márùn ún

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn obi awọn ọmọ Chibok lẹyin ọdun marun un ti gba ọdọ pasito lọ fun adura itusilẹ fun awọn ọmọ Chibok.
Awọn to le ni ọgọrun un lo ṣi wa ni panpẹ awọn ikọ Boko Haram lẹyin ti wọn ji wọn gbe ninu ile iwe wọn lọdun 2014.
Awọn obi awọn ọmọ Chibok lasiko ti wọn n ba Adaobi Tricia Nwaubani sọrọ ni ọrọ awọn kii se oju lasan mọ ni awọn se gba ọdọ Pasito ati Woli T.B. Joshua lọ lati ba wọn sawari awọn ọmọ wọn to wa ni panpẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn obi awọn ọmọ ile iwe Chibok, Yakubu Nkeki ni ibanujẹ ati ẹdun ọkan lo jẹ fun awọn nitori lẹyin ọdun marun un, ọgọrun un awọn ọmọ naa lo si wa ni panpẹ
Ni eyi ti lara awọn mọlẹbi awọn ọmọ wọnyii si ti ku nipase iku ojiji, ijamba ọkọ, aisan ati ikọlu awọn Boko Haram si awọn agbeegbe wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP
Arakunrin Nkeki ni awọn obi mẹrinlelọgbọn lo ti papoda lati igba ti ikọ Boko Haram ti ji awọn ọmọ wọn gbe si isinyii.
O fikun un pe ija ati asọ lo maa n waye lọjọọjọ ipade awọn obi naa, eleyii ti ko jẹ ki wọn fi imọ sọkan. Eyi lo mu ki wọn gba ile ijọsin T.B Joshua lo ni ilu Eko lati beere iranwọ lọdọ Ọlọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaga ẹgbẹ awọn obi awọn ọmọ ile iwe Chibok fikun un wi pe ipa awọn ti pi.
Bakan naa ni ijọba ti gbiyanju amọ ko tii si ọna abayo, amọ awọn gba Ọlọrun gbọ nitori yoo gbọ adura awọn ati wi pe awọn ọmọ naa yoo pada wale layọ ati alaafia.
Lara awọn to lo si ilu Eko fun adura lọdọ pasitọ T.B. Joshua ni alagbatọ Leah Sharibu to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla to wa ni panpẹ Boko Haram lati oṣu keji, ọdun to kọja lasiko ti wọn ji eniyan to ju ọgọrun un gbe lo nile iwe rẹ ni ilu Dapchi, ni ipinlẹ Yobe.

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ikọ Boko Haram ko lati fi Leah Sharibu silẹ lẹyin ti wọn yọnda awọn iyoku rẹ nitori ọmọ naa kọ lati fi ẹsin Kristẹni silẹ fun ẹsin musulumi ki wọn le tu silẹ lahamọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lasiko ayajọ ọdun karun un awọn ọmọ Chibok naa ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣalaye pe oun n sa ipa rẹ lati rii wi pe awọn to wa ni panpẹ Boko Haram naa gba itusilẹ laipẹ.
Obi àwọn ọmọdebinrin Chibok ṣi ni igbagbọ ninu Olọrun pe lọjọ kan ni awọn yoo foju kan awọn ọmọ awọn ti wọn jẹ mejilelaadọfa (112) laipẹ.
Ko pẹ lẹyin ti wọn ji awọn ọmọ yii gbe ni awọn obinrin kan ko ara wọn jọ pẹlu akọle "ẹ da ọmọbinrin wa pada: Bring back our girls).
















