Chibok girls: 'Ìjọba ń ṣe bí ẹni pé ọ ń ṣe àwọn òbí tí Boko Haram kọ lọ́mọ́ ló lóore ni'

Oríṣun àwòrán, STEFAN HEUNIS
Mejilelaadọfa ọmọbinrin Chibok ti ikọ Boko Haram ji gbe ni ọdun marun un sẹyin ni o ṣi wa ni igbekun, ṣugbọn awọn obi wọn ti fi ẹsun kan ijọba apapọ wipe wọn ko tilẹ náání àwọn mọ.
Agbẹnusọ fun awọn obi naa, Manasseh Allen sọ fun BBC Yoruba wipe ọdun mẹta sẹyin ni ijọba fun awọn ni iroyin bii igbesẹ lati wa awọn ọmọ to ku si igbekun ṣe n lọ.
O ṣalaye wipe awọn ko ti i gbọ nkankan lati ọdọ ijọba apapọ lati ọdun 2017 nigba ti Boko Haram da awọn mejilelọgọrin lara awọn ọmọbinrin naa silẹ.
Allen ni, nigba miiran, ijọba yoo ba awọn oniroyin sọrọ laiba awọn obi gan ti ọrọ kan sọ nkankan.
O ni, "Àwọn obi awọn ọmọbinrin to ku ni ijọba ti pa wọn ti kan. Ọrọ naa bi awọn obi ti ọrọ kan ninu de ibi pe, wọn ko fẹ ba awọn oniroyin sọrọ mọ. Wọn ni ijọba n ṣe bi ẹni pe wọn n ṣe wọn loore ni ti wọn ba gbe igbesẹ lati gba wọn ninu igbekun Boko Haram."
Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ni Boko Haram ji gbe ní ọdun mẹrin - Ajọ Iṣọkan Agbaye
Ninu iroyin miiran, ajọ Iṣokan Agbaye, (UN) ti ni awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn jẹ mẹtala si mẹtadilogun bii ẹgbẹrun mẹta ati aabọ ni awọn janduku ji gbe ni aarin ọdun 2013 si 2017.
Ajọ naa gbe atẹjade naa jade ni Ọjọbọ ninu eyi to ti ṣalaye wipe ni ọdun 2018 nikan, ọmọde to le ni irinwo ni o ku sinu laasigbọ ọke ọya.








