Ikọlu mẹfa ti o ti waye lawọn ileewe girama lorilẹede Naijiria

Yara ikẹkọ to ti di ahoro lẹyin ikọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ igba ni ijọba ti ti ileewe pa nitori ikọlu awọn agbebọn lorilẹede NAijiria

Ikọlu alẹ ọjọ aje nibi ti awọn agbebọn ikọ adukukulaja Boko Haram ji awọn ọmọ ileewe kan ko ni ileewe girama Government Girls Secondary School, ni ilu Dapchi, ipinlẹ Yobe kii ṣe akọkọ iru rẹ.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn ikọlu to ti waye si awọn ileewe lorilẹede Naijiria laarin asiko ti gulegule awọn ikọ Boko Haram bẹrẹ lorilẹede naa.

Mẹfa ninu wọn ni yi.

Ni ou kejila ọdun 2011

Kilaasi to wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ikọlu loniran an ran lo ti waye lawọn ileewe girama lorilẹede Naijiria

Ninu ikọlu kan ti awọn eeyan woye wipe o ṣeeṣe ko jẹ ikọlu lati gba ẹsan oniruuru ikọlu awọn ikọ Boko Haram si awọn ṣọọṣi ni apa ariwa orilẹede Naijiria, awọn eeyan kan ju ado oloro atọwọda si ileewe ẹkọ larubawa kan ni ipinlẹ Delta lasiko ti awọn akẹkọ naa fi n kẹkọ.

Akẹkọ meje lo farapa ninu iṣẹlẹ yii, mẹfa ninu wọn lo jẹ ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹsan lọ.

Ni ou keje ọdun 2013

Awọn ọmọbinrin Chibok ti wọn da pada joko ninu aworan yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lara awọn ọmọbinrin chibok ti wọn ji gbe ti pada wale

Awọn agbebọn kan ti awọn eeyan gbagbọ pe wọn wa lara ikọ Boko Haram pa awọn eeyan mejilelogoji, pupọ ninu wọn si jẹ akẹkọ ni ilu Mamudo.

Iṣẹlẹ yii waye lasiko ti awọn agbebọn naa fi kọlu ileewe girama kan ni ipinlẹ Yobe.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni n ṣe ni awọn agbebọn naa dana sun awọn eeyan naa laaye.

Ni ou keji ọdun 2014

Ọkunrin kan duro ni iwaju lleewe kan ti wọn kọlu.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, An agbebọn Boko Haram kọlu ileewe Government Girls Secondary School, Dapchi, Yobe

Awọn agbebọn kan ti wọn jẹ ọmọ ikọ Boko Haram dana sun akẹkọ mọkandinlọgọta ni ileewe girama kan ni ilu Buni Yadi nitosi Damaturu tiiṣe olu ilu ipinlẹ Yobe.

Awọn ọlọpa sọọ nigba naa wipe ajodeeru ni awọn eeyan naa jo.

Ni oru ọjọ kẹrinla si ikẹẹdogun ou kẹrin ọdun 2014

Awọn eeyan gbe iwe alakọle dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orilẹede Naijiria ti wa labẹ ikọlu Boko Haram fun ọdun diẹ

Awọn agbebọn ikọ Boko Haram kan ji awọn akẹkọ obinrin gbe ni ileewe girama ijọba to wa ni ilu Chibok ipinlẹ Borno.

Bi o tilẹ jẹ wi pe wọn ti ri gba pada lara awọn ọmọobinrin wọnyii, sibẹ awọn kan ṣi wa lahamọ awọn ikọ adukukulaja naa. Kaakiri origun mẹrẹrin agbaye ni awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii eleyi to sọọ di ọkan pataki ninu ohun ti awọn eeyan fi ṣe odinwọn eeyan ti wọn dibo fun lasiko idbo apapọ orilẹede Naijiria lọdun 2015.

Ni ou kọkanla ọdun 2014

aworan ipolongo ibo fun Buhari ati Jonathan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọkan pataki ninu ohun ti an eeyan fi se odinwọn eeyan ti wọn dibo fun lasiko idbo apapọ orilẹede Naijiria lọdun 2015

Ko din ni eeyan mẹrindinlaadọta to ku ti awọn mọkandinlọgọrin miran si fi ara ṣeṣe yanayana nigba ti awọn ọmọ ikọ Boko Haram kan to so ado oloro mọra lọ pa ara rẹ lasiko ti awọn akẹkọ ko ara jọ si ileewe Government Science Secondary School.

Ẹni to so ado iku mọra yii wọ aṣọ ileewe yii lọjọọ naa.

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni gomina ipinlẹ naa ti awọn ileewe ijọba gbogbo to wa lagbegbe naa pa.

Ni ou karun ọdun 2017

Awọn ọkọ ọmọ ogun n rin lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ologun ti bẹrẹ sii ni gbogun ti awọn ik boko haram

Awọn agbebọn kọlu ileewe girama Government Model College, Igbonla, Epe ni ipinlẹ Eko.

Awọn agbebọn naa ti wọn jọ marundinlogun niye ji akẹkọ mẹfa to jẹ ọkunrin gbe.

Ikọlu ọhun waye ni nkan bii osu meje lẹyin ti awọn agbebọn naa ti kọkọ kọlu ileewe yii kan naa ti wọn si ji igbakeji ọga agba ileewe naa, ati awọn akẹkọ mẹrin.