Kí ni òfin tí Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò afẹ́ tàbí lọ ra ọjà níbẹ̀ láti Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti gbé òfin tuntun léde fáwọn orílẹ̀ èdè kan tó fi mọ́ Nàìjíríà tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè náà yálà fún àbẹ̀wò tàbí láti lọ ra ọjà.
Òfin yìí ló de àwọn tó bá fẹ́ gba físà B1 tàbí B2, tí wọ́n yóò sì máa san owó tí iye rẹ̀ fẹ́ẹ̀ tó mílíọ̀nù méje sí mílíọ̀nù méjìlélógún náírà ($5,000 - $15,000) kí wọ́n tó le rí físà gbà.
Ohun tí owó náà wà fún ni pé wọ́n máa gba owó náà sọ́wọ́ títí ẹni náà fi máa padà sí Nàìjíríà.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé láti lè ri pé àwọn tó ń wọ Amẹ́ríkà láti àwọn orílẹ̀ èdè kan, tó fi mọ́ Nàìjíríà kò lò kọjá àsìkò tí wọ́n fún wọn lọ.
Ta ni yóò san owó náà?
Àwọn tó ń bèèrè fún físà láti lọ ṣe ìrìnàjò afẹ́ àtàwọn tọ fẹ̀ lọ ra ọjà ni òfin tuntun yìí bá wí, kò kan àwọn tó fẹ́ gba físà láti lọ máa gbé Amẹ́ríkà pátápátá.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Amẹ́ríkà fi sójú òpó ayélujára wọn, wọ́n ní sísan owó náà kò túmọ̀ sí pé Amẹ́ríkà máa fún wọn ní físà.
Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá san owó láì gba àṣẹ látọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìrìnnà Amẹ́ríkà ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má rì í owó wọn gbà padà.
Nínú àwọn orílẹ̀ èdè méjìdínlógójì tí Amẹ́ríkà fi léde pé òfin náà kàn, mẹ́rìnlélógún nínú wọn ló jẹ́ ilẹ̀ Africa tí Nàìjíríà náà sì wà lára wọn.
Ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ àmúṣẹ òfin yìí fún Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè kan.
Àwọn orílẹ̀ èdè wo ni òfin náà kàn?
Lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ìlànà tuntun náà kàn tí wọ́n sì máa bẹ̀rẹ̀ àmúṣẹ òfin náà lọ́jọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní ni Algeria, Angola, Antigua and Barbuda, Bangladesh, Benin, Bhutan, Botswana, Burundi, Cabo Verde, Central African Republic, Côte d'Ivoire, Cuba, Djibouti, àti Dominica.
Àwọn míì ni Fiji, Gabon, Guinea, Guinea-Bissau, Kyrgyzstan, Namibia, Nepal, Senegal, Tajikistan, Togo, Tonga, Turkmenistan, Tuvalu, Uganda, Vanuatu, Venezuela, àti Zimbabwe.
Ní oṣù Kẹjọ àti oṣù Kẹwàá ni àmúṣẹ òfin yìí yóò wáyé fáwọn orílẹ̀ èdè bíi The Gambia (11 October, Malawi, Mauritania, São Tomé and Príncipe, Tanzania àti Zambia.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí Amẹ́ríkà láti àwọn orílẹ̀ èdè yìí yálà fún ìgbafẹ́ tàbí láti lọ ra ọjà, onítọ̀hún yóò san $5,000, $10,000 tàbí $15,000.
Lásìkò tí ẹni náà bá lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni wọ́n máa sọ iye tí yóò san fún-un.
Bákan náà ni wọ́n ni ẹni náà gbọdọ̀ ṣe àgbékalẹ̀ fọ́ọ̀mù Department of Homeland Security's Form I-352, tó sì gbọdọ̀ gbà láti san owó náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ pé onítọ̀hún gbọdọ̀ bá àwọn pápákọ̀ òfurufú Amẹ́ríkà wọ orílẹ̀ èdè náà ni tó fi mọ́ Boston Logan International Airport, John F. Kennedy International Airport ní New York, àti Washington Dulles International Airport ní Virginia.
Gẹ́gẹ́ bí ìdarí náà ṣe sọ, tí ẹni náà bá kúrò ní Amẹ́ríkà lọ́jọ́ tí wọ́n fún-un tàbí ṣáájú ọjọ́ náà ló máa gba owó rẹ̀ padà ṣùgbọ́n tó bá kọjá ọjọ́ tí wọ́n fún-un, wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n wọ Amẹ́ríkà.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí Amẹ́ríkà fòfin de Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdé míì.
Fún Nàìjíríà, US ní ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí tó fi mọ́ Boko Haram àti ISIS láwọn apá ibìkan wà lára ìdí tí wọ́n ṣe gbé òfin náàkalẹ̀.















