Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìpàdé ìdákọ́nkọ́ tí Makinde ṣe pẹ̀lú Atiku àti Babangida

Oríṣun àwòrán, @Chibuezechidube/X/Presidency
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ati Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar ṣe ipade idakọkọ pẹlu Olori ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ, Ajagun fẹyinti Ibrahim Babangida nile rẹ to wa niluu Minna nipinlẹ Niger lanaa ọjọ Iṣẹgu ọjọ kẹwaa oṣu Kinni yii.
Ọpọ eeyan lo ti n beere wi pe ki ni ipade Makinde to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ati Atiku ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC pẹlu Babangida le da le lori.
Wọnyii ni ohun ti a mọ nipa ipade idakọnkọ to waye naa laarin Makinde, Atiku ati Babangida.
Ohun ti a mọ nipa ipade idakọnkọ to waye laarin Makinde, Atiku ati Babangida
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku ti sọ pe abẹwo oun si ipinlẹ Niger da lori ọna lati jẹ ki ẹgbẹ oṣelu ADC fẹsẹ mulẹ ni ipinlẹ naa.
Atiku ni abẹwo oun ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu bo ya oun yoo dupo aarẹ lọdun 2027.
Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo ọdun 2023 sọ pe ohun to jẹ oun logun bayii ni bawọn ọmọ Naijiria ṣe n pe fun gbigbe esi idibo jade lori kọmputa lati awọn ibudo idibo lẹsẹ kẹsẹ, eyi ti ile aṣofin agba l'Abuja ko gba wọle pata pata.
Atiku ni lilo ẹrọ kọmputa lati gbe esi ibo sori ayelujara lẹsẹ kẹsẹ yoo dẹkun awuyewuye to maa n jẹyọ ninu eto idibo Naijiria ni gbogbo igba.
Atiku ni gbigbe esi ibo sori ayelujara yoo mu adinku ba laaṣigbo to maa n saba ṣẹlẹ lasiko eto idibo ni Naijiria.
''A nilo gbogbo ẹgbẹ oṣelu alatako lati karamọ ọrọ atunṣe ofin eto idibo ti ile aṣofin agba l'Abuja ko ṣe daadaa yii.
A ko gbọdọ jẹ ki ọrọ naa tii sinmi bi ile aṣofin agba ti ṣe gbe e ju sẹgbẹ kan.
Nnkan tawọn ọmọ Naijiria n beere fun ko ruju rara, ohun ti wọn fẹ ni pe ki ajọ eleto idibo INEC maa lo ẹrọ kọmputa lati gbe esi ibo sori itakun ayelujara lẹsẹ kẹsẹ.
Ohun ti ile aṣofin buwọlu bayii ni lilo ẹrọ kọmputa ati fifi ọwọ ṣe akojọpọ esi ibo ni Naijiria.
Laisi ani-ani, nnkan ti ile aṣofin buwọlu yii yoo da ede-ai-yede silẹ,'' Atiku lo sọ bẹẹ.
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ wa kepe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako yooku lati tako atunṣe ti ile aṣofin agba ṣe lori ofin eto idibo ki wọn si beere fun lilo kọmputa lati gbe esi ibo sori itakun ayelujara lẹsẹ kẹsẹ.
Atiku ni nnkan ti ẹgbẹ oṣelu ADC n ṣe bayii ni lati ko awọn eeyan jọ lẹsẹ kuuku ati lati jẹ ki ẹgbẹ naa fẹsẹ mulẹ daadaa kaakiri orilẹede Naijiria.
Gomina Makinde ipinlẹ Oyo ko bawọn akọroyin sọrọ ni tiẹ lẹyin ipade naa.
A gbọ pe Makinde si duro ninu ile Babangida lẹyin ti Atiku ti kuro nibẹ.



























