Nàìjíríà gba ipò 36 nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu ti gbilẹ̀ julọ lágbàáyé

Tinubu ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn orilẹ-ede Afrika miran to tun wa ninu akọsilẹ naa ni Cape Verde tabi Cabo Verde to ni maaki mejilelọgọta to si dara julọ ni Afrika sugbọn to wa ni ipo kejilelọgbọn nil agbaye.

Orilẹ-ede Botswana ati Rwanda naa wa ni ipo ọkanlelogoji ati maaki kejilelọgọta.

Maaki kẹrindinlọgbon ni Naijiria gba ninu ọgọrun un ni eyi ti wọn fi gbe ipo kejilelogoje'

Orilẹde Kenya san ju Naijiria lọ pẹlu ipo 130 nigba ti Burkina faso gbe ipo 84 pẹlu maaki ogoji ninu ọgọrun un kan.

Bawo ni ipo Naijiria ṣe buru to?

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti wà ní ipò kẹrìndínlógójì (36th) nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu ti gbilẹ̀ jùlọ ní àgbáyé.

Èyí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí àjọ Transparency International gbé jáde láti fi ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà ìbàjẹ́ gbilẹ̀ níbẹ̀ fún ọdún 2025.

Ipò kejìlélógóje (142) ni Nàìjíríà wà nínú àwọn orílẹ̀ èdè méjìlélọ́gọ́sàn-án (182) tí àjọ náà ṣe àgbéyẹ̀wò wọn láti mọ àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu kò wọ́pọ̀ níbẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìgbéléwọ̀n àjọ náà, pọ́ìntì mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ni Nàìjíríà ní, èyí tó jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Cameroon, Guatemala, Guinea, Kyrgyzstan àti Papua New Guinea.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹ́gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ, èyí ṣàfihàn ìpèníjà tó ń kojú ìṣèjọba.

Ìwádìí náà ṣàfihàn pé orílẹ̀ èdè Denmark ló léwájú nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu kò wọ́pọ̀ níbẹ̀, lẹ́yìn náà ló kan Finland, Singapore àti New Zealand.

Kò sí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Africa kankan níwájú nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu kò wọ́pọ̀ níbẹ̀ tí èyí sì túmọ̀ sí pé àwọn orílẹ̀ èdè Africa ní iṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe lórí ètò ìṣèjọba.

Lára àwọn orílẹ̀ èdè Africa tí ìwà àjẹbánu sẹ́ pẹ́rẹ́ níbẹ̀ ni Seychelles, Cabo Verde àti Botswana tí wọ́n wà ní ipò 68, 62 àti 58.

Fún ọdún 2025, àwọn orílẹ̀ èdè tó léwájú nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwà àjẹbánu pọ̀ níbẹ̀ jùlọ ní àgbáyé ni South Sudan, Somalia àti Venezuela.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà yìí, adarí ẹ̀ka ill Africa ní àjọ Transparency International, Paul Banoba sọ pé àwọn aláìní ni ìwà àjẹbánu tó ń wáyé lẹ́ka ìjọba ń ṣe ìpalára fún jùlọ.

Ó ní àwọn ìjọba nílẹ̀ Africa nílò láti tètè gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ri dájú pé wọ́n fòpin sí àwọn ohun tó ń mú ìwà àjẹbánu gbilẹ̀, kí wọ́n mú ìgbèrú bá àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ ìjọba.

Ó fi kun pé ìwà gbangba làṣá ń ta gbọdọ̀ jẹ́ àmúlò láti dá ààbò bo àwọn aráàlú àti ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn aláìní.