Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ismail Abba Yusuf alága àjọ Hajj tuntun tí Tinubu yàn

Oríṣun àwòrán, @Yussuf
Aarẹ Bola tinubu ti kede alaga tuntun fun ajọ to n risi lilọ si Meka fun irinajo mimọ awọn ọmọ Naijiria.
Aṣoju Naijriia loke okun tẹle ni Ismail Abba Yusuf ti Aarẹ Tinubu ni ko lọ maa dari ajọ National Hajj Commission (NAHCON) naa bayii.
O ni ki Ismail lọ fun ifọrọwanilẹnuwo lọdọ awọn Asọjuṣofin nile Igbimọ ni Abuja ki o to dipe o maa le bẹrẹ iṣẹ lẹyin ti wọn ba buwọlu iyansipo rẹ.
Aarẹ Tinubu ti fi lẹta ranṣẹ si Godswill Akpabio to jẹ Adari Ile Igbimọ Asofin agba ni abuja pe ko gbe ọrọ iyansipo naa wo bayii.
Ismail abba yusuf yii ni yoo dipo ọjọgbọn Abdullahi Usman to kọwe fipo sile lọsẹ yii lẹyin ti wọn fẹsun ajẹbanu kan an.
Osu mẹrinla pere ni Ojọgbọn Abdullahi Usman lo nipo naa ko to kuro nibẹ.
Tani Aṣoju orilẹ ede Yusuf Abba Ismail?
Ambasadọ Yusuf jẹ aṣoju orilẹ ed eNaijiria ni Republic of Turkiye nibi ti Aarẹ Tinubu ti lọ ṣabẹwo laipẹ yii.
O ṣoju Naijiria nibẹ laarin ọdun 2021 si ọdun 2024.
Awọn aṣojuṣofin Naijiria yoo gbe e yẹwo gẹgẹ bii alakala ofin Naijiria ti section 3 (2) to da ajọ NAHCON silẹ.
Ismail Abba yusuf jẹ ọkan lara awọn oṣiṣe Naijria to jẹ aṣoju orilẹ ed eyii ti ọpọ maa n bọwọ fun.
O ti ṣiṣẹ asọju Naijiria ni Asia, Europe, Latin America ati Middle East fun ọpọlọpọ ọdun.
Bayii to n di adari ajọ alalaji yii sọ o di ẹni to n kuro nipo aṣoju si adari ẹsin.
ọpọ nkan nipa Ismail ni ko si lojutaye nitori ohun to nii ṣe pẹlu iṣe asoju orilẹ ede to jẹ fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Aarẹ Muhammadu Buhari lo yan Ismail gẹgẹ bii asoju Naijiria si Turky lọdun 2021.
Alága àjọ Hajji, Abdullahi Saleh Usman, kọ̀wé fipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, NAHCON
Alaga ajọ to n risi iṣẹ Hajji lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Abdullahi Salah Usman ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Ọpọ iroyin lo jade lọjọ Aje pe Usman kọwe fipo rẹ silẹ nitori ọpọ ẹsun ti wọn fi kan.
Lọjọ Iṣẹgun, ọkan ninu awọn alaṣẹ ajọ naa fidi iroyin naa mulẹ fun BBC ṣugbọn ko sọ pato ohun to fa ti igbesẹ naa fi waye.
Kini o n ṣẹlẹ ni ajọ Hajj Commission Naijria ?
Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ki lo de ti iwa ajẹbanu fi n run lara awọn olori ajọ irinajo lọ silẹ mimọ Meka lati igba diẹ wa bayii?
Iwadii fihan pe awọn ẹsun ti wọn fi kan Usman ni wọn fi ransẹ si ọfisi aarẹ Naijiri lati ọdọ awọn aṣoju ajọ naa.
Lati bi ọdun mẹta si mẹrin bayii, ọpọ ayipada lo ti wa ni ajọ NAHCON, to si jẹ pe alaga mẹta lo ti di ipo naa mu lati asiko naa ṣugbọn wọn ko ki n pari saa wọn ki wọn to kọwe fipo silẹ.
Ni ọdun 2024, Aarẹ orilẹede Naijiria yan Sheikh Abdullahi gẹgẹ alaga ajọ aa lẹyin ti wọn yọ Jalia Arabi to n dele fun alaga.
Alaga tẹlẹ naa ni wọn fẹsun kan pe o kowo jẹ, ti ọwọ ajọ EFCC si ransẹ pe ko wa wi tẹnu rẹ, ti iwadii si ti bẹrẹ lori ẹsun naa.
Ajọ naa ni owo toto 300,000 Riyals ni wọn ri lakata alaga ati awọn agba oṣiṣẹ kan ninu ajọ Hajj
























