Èèyàn 80 móríbọ́ lọ́wọ́ ikú bí bààlúù tó ń lọ sí Port Harcourt ṣe balẹ̀ sí Benin

Oríṣun àwòrán, Others
Ori ko eeyan ti ko din ni ọgọrin (80) yọ lọwọ iku lonii Ọjọru, ọjo kọkanla oṣu Keji ọdun 2026, bi baaluu to n gbe wọn lọ si Port Harcourt ṣe koju iṣoro to si pada balẹ si Benin.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ilu Eko ni ọkọ baaluu Arik Air Boeing 737-700 naa ti gbera, ṣugbọn ko le de Port Harcourt to n lọ to fi koju iṣoro laaarin ọna.
Apẹẹrẹ ti awakọ baaluu naa ri lati ara ẹnjiini ọkọ ọhun lo jẹ ko pinnu pe o san ki baaluu ọhun balẹ si papakọ ofurufu to wa nitosi, gẹgẹ bi ofin irinna ofurufu, ju ko tẹsiwaju ninu irinajo naa lọ.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa, Banji Ola, ṣalaye pe :
"Baaluu naa n lọ si Port Harcourt lasiko ti ikọ to n ṣakoso rẹ ṣakiyesi nnkan kan lati apa osi ẹnjinni rẹ.
"Ariwo nla kan to dun gbaamu lo tẹle eyi. Lati dena ijamba, ikọ naa dari ọkọ gba Benin."
Ko sẹni to farapa ninu awọn ero ọkọ naa to jẹ ọgọrin bo ṣe wi, gbogbo wọn ni wọn sọ kalẹ layọ.
Bakan naa lo ni eto ti wa lati ko awon ero ọkọ to n lọ si Port Harcourt naa lọ si ibudo wọn.
Wọn tọrọ aforiji fun ohun to ṣẹlẹ yii, pẹlu alaye pe alaafia awon eeyan naa lo jẹ awọn logun julọ.
Ninu ọrọ ajọ to n ri si aabo ati iwadii ni Naijiria (Nigeria Safety Investigation Bureau) NSIB, wọn ni ikọ to n dari baaluu naa tete gbe igbesẹ to le dena ijamba, nipa didari ọkọ yii gba Benin.
Adari ẹka ikede NSIB; Bimbo Oladeji, sọ pe iṣoro kan lo ba ẹnijinni ọkọ naa lori ìrìn.
O fi kun un pe iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.
"NSIB n ṣiṣẹ pẹlu ajọ to n ri si irinajo ofurufu ni Naijiria; Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA), ileeṣẹ Arik Air ati awọn tọrọ kan lori iṣẹlẹ yii, lati mọ ohun to fa a.
" Abọ iwadii naa yoo jade laarin ọgbọn ọjọ ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin ICAO (Annex 13 ). Abọ iwadii to kangun yoo si jade leyin iwadii naa."
Bẹẹ ni Oladeji wi.


























