Wọ́n rí òkú akọrin ẹ̀mí àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mẹta nínú 'studio' kan l'Eko, ọlọ́pàá mú afurasí kan

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu afurasi kan lori iku akọrin ẹmi ati eeyan mẹta mii ti wọn ri oku wọn ninu yara ti wọn ya sọtọ fun orin kikọ lagbegbe Ajah niluu Eko lọsẹ to kọja.
Akọrin ẹmi naa, Matthew Ogundele atawọn mẹta mii, Itunu Ogundele, Joseph Sanya, ati akọroyin ori ayelujara kan, Matthew Awosanya, tawọn eeyan mọ si JoesTv ni wọn ṣadeede ri oku wọn ninu yara ti wọn n lo fun orin kikọ to wa ni ile HFP Shopping Complex ni Abraham Adesanya ni Ajah.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Abimbola Adebisi, fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan lo kọkọ fi ọrọ naa to agọ ọlọpaa to wa ni Ajah leti.
Amọ, SP Adebisi ni ọrọ naa ti de ọdọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ SCID ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to wa ni Panti, Yaba fun iwadii lẹkunrẹrẹ bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹni to ṣagbatẹru ode tawọn akọrin ẹmi naa atawon akẹgbẹ rẹ ti lọ ṣere ti wa ni atimọle ọlọpaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹni to ni yara studio ti wọn n lo fun orin kikọ naa, Akintayo Akinbola, lo fi iṣẹlẹ ọhun to ọlọpaa leti.
Wọn ni ẹni lo sọ fawọn ọlọpaa pe awọn to doloogbe naa wa lara awọn akọrin ti wọn ṣere nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti iyawo rẹ ṣagbatẹru.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, ọjọ ti lọ lalẹ nigba tawọn akọrin naa sẹre tan, eyi to mu wọn sun ninu yara ti wọn n lo fun orin kikọ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni laaarọ ọjọ keji ti ẹni to ni yara orin ti wọn sun si naa de ibẹ lo ba oku wọn nibẹ.
Ni ile iwosan Mainland to wa ni Yaba ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹrẹẹrin ti ku, wọn si ti gbe oku si mọṣuari.
Ọpọ eeyan papaa julọ lori ayelujara lo ti n pe fun iwadii ati idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa.
Ẹwẹ, awọn kan sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe eefin ẹrọ jẹnẹretọ to wa lẹnu ọna yara ti wọn n lo fun orin nigba ti wọn sun lo ṣekupa wọn.
Iroyin kan tun fidi rẹ mulẹ pe ẹjẹ n jade lati imu, eti ati ẹnu awọn eeyan nigba ti ko si si apa kankan lara wọn.



























