Wo àwọn ọjà tí ìjọba Eko tìpa nítorí ìdọ̀tí

Aworan òketè idọti ati ẹnikan to n kọja niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi imototo ṣe ṣe pataki ninu ile naa ni ko yọ ọja silẹ, nitori ibẹ ni araalu ti n ra ohun jijẹ ati lilo. Sugbọn nigba ti imọtoto ba mẹhẹ lọja, ijọba yoo gbe igbesẹ ti yoo kọ awọn eeyan ọja naa ni ohun to yẹ.

Ọpọ igba ni ijọba Eko maa n kilọ iwa idọti naa fun awọn olugbe agbegbe ati ọja, pẹlu awọn olokowo adani, nipa lilo abala ofin imọtoto ti ọdun 2017 to koro oju si dida idọti lọna aitọ.

Lọjọ Aiku ni Kọmiṣanna to n ri si ayika l'Ekoo, Tokunbo Wahab, kede pe ijọba ti ti gbajugbaja ọja nnkan elo mọto ti I ṣe 'Ladipo Spare Parts Market' pa.

O ni ọpọ igba ni ijọba ti ti ọja naa nitori idọti ti wọn n danu lọna aitọ ati tita ọja loju ọna.

Wọnyi ni awọn ọja ti ijọba ti tipa l'Eko ri nitori titipa si ofin imọtoto

  • . Awọn ṣọọbu ọja ⁠Ifesowapo, Mile 12
  • ⁠Awọn ṣọọbu lopopona Demurin, Ketu
  • Ojule kẹfa, Opopona Demurin, Ketu
  • Ọja ⁠Ifelodun, Ketu
  • ⁠Ibadan Unit 1 park .
  • Ketu Tipper Garage.
  • Ọja Itedo, Lekki
  • Ọja Sabo, Yaba
  • Ọja Gorodom ati Alagbafọ, Erekuṣu Eko
  • Oko Oba Abattoir, Agege
  • Ọja Ebute-Ero (Block N)

Awọn mi-in ni

  • 1 Ọja Erukan, Mile 12
  • 2 ⁠Oja Oba, Ketu
  • 3 ⁠Ọja Owoseni Tundas
  • 4 ⁠Ọja Oba Ogunjobi, Mile 12
  • 5 ⁠Awọn ṣọọbu nibudokọ BRT Terminal, Mile 12
  • 6⁠Awọn ṣọọbu nibudokọ Mile 12
  • 7 Ọja ⁠ibudokọ Ketu (6 plazas)