Àwọn agbésùnmọ̀mí ṣekọlù sí Kóro ní Kwara, kọlu Ọlọ́dẹ, sekúpa ẹṣọ Aṣọgbo, dáná sun ọ̀kadà mọkanla ní Kwara.

Oloogbe Samuel Abimbola, Asogbo Kwara ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, @Forest Gard. Oloogbe Samuel Abimbọla

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àwọn agbésùnmọ̀mí ti ṣe ikọlu si agbegbe Koro nijoba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara.

Wọn tun kọlu awọn Olọdẹ, ẹsọ aṣọgbo yatọ si pe wọn sekúpa ẹṣọ asogbo n kan nibẹ, ki wọn to tún dáná sun ọ̀kadà mọkanla ní Kwara.

Yoruba bọ wọn ni bi ati n jẹ ekuru ko tan lawo ni wọn tun n gbọn ọwọ rẹ si lọrọ awọn agbebọnja yii ri ni ipinlẹ Kwara.

Lana ọjọ Aiku, Sunday, ọjọ kẹjọ, oṣu keji, ọdun yii lawọn agbesunmọmi tun kọ lu awọn ọlọdẹ, fijilante, ati awọn ẹṣọ aṣọgbo ni ilu Koro ijọba ibilẹ Ekiti ipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bi ẹni tọrọ soju ẹ, Ogbeni Sunday Olatunji to ba aṣoju kọroyin ile iṣẹ wa BBC Yorùbá sọrọ ti wi pe ni nnkan bi ago mọkanla owurọ ana ni iṣẹlẹ naa sẹlẹ.

O salaye pe, awọn ọdẹ ibilẹ, awọn fijilante ati awọn ẹṣọ aṣọgbo lo lọ koju awọn agbesunmọmi naa ninu igbo.

*Bawo lo se ṣẹlẹ gan?

Lọjọ Aiku, Sunday, ọjọ kẹjọ, oṣu keji ọdun yii ni awọn ara ilu naa ta awọn ọdẹ ibilẹ lolobo pe, awọn ri awọn agbesunmọmi ninu oko.

Gẹgẹ bi ẹni kan tọrọ soju ẹ, ọgbẹni Sunday Ọlatunji ṣe wi. pe : -

Bawọn ara ilu naa ṣe ta awọn Ọdẹ lolobo lo mu ki awọn Ọdẹ ke si awọn fijilante ati awọn ẹṣọ aṣọgbo ti wọn si ta mọra lati lọ koju wọn.

O salaye pe, bi wọn ṣe lọ koju wọn ninu igbo ni wọn gbe ọkada mọkanla ti wọn gbe lọ si ibi kan ti wọn si fẹsẹ rin lọ ba wọn.

Ṣugbọn wọn ko mọ pe, awọn agbebọnja naa ti gọ de wọn ni oju ọna ti wọn yóò gba kọja lojiji, ni wọn yinbọn lu awọn Ọlọdẹ.

Ta ni o ku ninu ikọlu naa?

Ogbeni Olatunji fikun un pe pe ọrọ di bo lọ yami ninu Igbo naa.

Pẹlu alaye pe, ọkan lara awọn ẹṣọ aṣọgbo' Forest Guard' ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Abimbọla padanu ẹmi rẹ ninu akọlu naa.

O sọ pe, gbogbo Ọkada mọkanla ti awọn Ọdẹ naa gbe lọ lawọn agbebọnja naa dana sun di eeru.

O tun ṣalaye pe jinnijinni ti bo awọn eeyan ilu Koro nítorí akọlu naa.

*Kini ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ ni ilu Koro.**

Nnkan bi ọdun meji sẹyin lawọn agbebọnja yawọ ilu Koro ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara ti wọn si yinbọn pa Ọba ilu naa.

Awọn agbọnja naa tun ji Olori ọba ilu naa ati ọmọ ọdọ wọn gbe lọ.

Akọlu da ibẹru bojo ṣọkan awọn ara ilu eyi to mu Gomina ipinlẹ Kwara Abdulrahman Abdulrazak ati kọmisọna àjọ ọlọ́pàá Igbana Victor Ọlaiya sabẹwo si ilu naa.

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu lawọn agbebọnja naa to yọnda Olori ati ọmọ ọdọ wọn ti wọn ji gbe.

Lati igba naa ni awọn eeyan ilu Koro ti n gbe ninu ibẹru.

Ilu Koro ko jinna si ilu Eruku tawọn ajinigbe ti ji awọn olujọsin gbe lọdun to kọja ninu ile ijọsin.

Bẹẹni ilu Koro sunmọ ipinlẹ Kogi to si paala pẹlu ilu Ẹgbẹ ni ipinlẹ Kogi.