Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria, ẹ jẹ́ káwọn Amotekun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà l'Osun láti lè dènà irú ikọlù tó ṣẹlẹ̀ ní Kwara - Adeleke

Oríṣun àwòrán, Osun State Government/X
Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun ti kepe ọga ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun, wí pe ko jẹ k'awọn ẹṣọ eleto aabo Amotekun bẹrẹ iṣẹ pada latari iṣẹlẹ igbesunmomi to waye ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni ijọba ibilẹ Kaiama nipinlẹ Kwara.
Gomina Adeleke rọ ọga ọlọpaa pe ko gbẹsẹ kuro lori ofin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi de awọn ẹṣọ Amotekun nipinlẹ Osun lati dena iru iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe to waye niluu Woro ni ijọba ibilẹ Kaiama ni Kwara nibi ti ko din ni eeyan ọgọjọ tawọn agbesunmọmi ṣekupa.
Gomina Adeleke to fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed, fi sita, ṣalaye pe ofin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi de awọn Amotekun lo jẹ ki iṣẹlẹ ijinigbe to waye lagbegbe Ore Igbomina laipẹ yii waye.
Adeleke ni ileeṣẹ ọlọpaa ju awọn ọga ẹṣọ Amotekun si atimọle fun ọpọlọpọ oṣu lai gbe wọn lọ sile ẹjọ.
O ni awọn Amotekun mọ ọgbọn ti wọn maa n lo lati dena awọn janduku ajinigbe nipinẹ Osun papaa julọ lawọn ibode ipinlẹ Osun.
Gomina ni bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fofin de awọn Amotekun n fawọn ọdaran atawọn janduku agbebọn lanfaani lati maa ṣiṣẹ ibi wọn ni ipinlẹ Osun.
Adeleke to kepe ọga ọlọpaa lati gbẹsẹ kuro ofin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi de awọn Amotekun, sọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa gbe awọn ọga Amotekun to wa ni ahamọ lọ sile ẹjọ.
Gomina ipinlẹ Osun sọ pe aiṣiṣẹ awọn Amotekun lewu fawọn olugbe igberiko ni ipinlẹ Osun tori awọn janduku agbebọn yoo lanfaani lati ṣiṣẹ ibi wọn nigba kugba.
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Osun tun ti sọ pe awọn ẹṣọ eleto aabo ti wa lojufo bayii papaa julọ lawọn ibode ipinlẹ naa latari iṣẹlẹ laabi awọn agbesunmọmi to waye ni Kwara.
Adeleke ni awọn ẹṣọ eleto aabo ti duro wamuwamu lawọn ibode lati dena awọn janduku agbebọn to ba fẹ ṣe iru ijamba to ṣẹlẹ ni Kwara nipinlẹ Osun.
Gomina ko ṣai kẹdun pẹlu ẹbi awọn eeyan to ku nibi ikọlu to waye ni Kwara, o si tun kẹdun pẹlu ijọba ipinlẹ naa lori nnkan to ṣẹlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























