Ṣé lóòótọ́ ni àwọn ṣọ́jà America mú Sheikh Gumi ní pápákọ̀ òfurufú?

Sheikh Ahmad Gumi

Oríṣun àwòrán, Sheikh Ahmad Gumi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

L'Ọjọbọ ana ni fọto kan gori ayelujara, to ṣafihan ibi ti awọn ṣọja ilẹ America meji ti mu Sheikh Ahmed Gumi si aarin bii ẹni to ṣẹ.

Papakọ ofurufu kan ni aworan naa ṣafihan, pẹlu Sheikh Gumi ti awọn ṣọja oyinbo ko ni papamọra.

Fọto ọhun ko jade lasan, wọn tun fi ọrọ ti i lẹgbẹẹ to kede pe awọn ṣọja America ti mu Gumi ni papakọ ofurufu Naijiria kan.

Wọn ni lasiko ti Aafaa naa fẹ sa lọ si Turkey latari ajọṣepọ rẹ pẹlu awọn agbesunmọmi ni wọn mu un.

Ko pẹ rara ti fọto ohun fi kari aye, ti ọpọ eeyan si n fi ero ọkan wọn han si aworan naa.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe o daa bi America ṣe nawọ gan Gumi, wọn ni boya nitori ajọṣepọ rẹ pẹlu awọn agbesunmọmi naa ni wọn ṣe mu un.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe ohun to yẹ kijọba Naijiria ṣe tipẹ fun Sheikh Gumi ree, ti wọn fi isilẹ lai ṣe, to jẹ America lo ṣẹṣẹ wa ti ọhun waa mu un.

Ṣugbọn otitọ wo lo wa nidii ọrọ yii?

Sheikh Gumi ṣalaye ohun to ṣẹlẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi fọto yii ṣe gbode kan ti ero araalu lorii rẹ ko si fi ara rọ, Sheikh Gumi funra rẹ fi ọrọ lede laipẹ rara.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade to pe lori ọrọ naa, Gumi sọ pe ohun ti ko ba laakaye mu rara ni.

"Awọn ṣọja ilẹ America ko le mu mi ni Naijiria, ki lo fẹ fa a ti ologun America yoo fi waa mu mi ni Naijria, fun kin ni?"

"Ẹrọ 'Artificial Intelligence' (AI) ni wọn fi ṣe fọto yẹn, koda, ẹni ti ko tiẹ da nnkan kan mọ gan-an yoo mọ pe AI ni."

Bẹẹ ni Gumi ṣalaye.

O ni aworan aṣinilọna pata gbaa ni, ti ko si yẹ kawọn eeyan gba a gbọ.

Sheikh Gumi sọ pe wọn ko mu oun o, oun ṣi wa ni alaafia ati ominira ni Naijiria, irọ ni awọn to gbe fọto ọhun jade fi pa.

Tẹ o ba gbagbe, ọpọ igba ni Sheikh Gumi ti pe fun asọyepọ laaarin ijọba Naijiria ati awọn agbesunmọmi to n da omi alaafia orilẹede yii ru.

Nigba ti America sọ ado oloro si apa kan ipinlẹ Sokoto lọjọ ọdun Keresimesi to kọja, Sheikh Gumi tako o.

Awọn nnkan bẹẹ lo si mu ọpọ eeyan maa gbagbọ pe Sheihk Gumi ni ohun to n ṣe pẹlu agbesunmọmi ni Naijiria, bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni aafaa naa ti ni ko sohun to jọ bẹẹ rara.