Ẹ̀yin Gómìnà, ẹ ṣètò láti pèsè iṣẹ́, ètò ìlera alábọ́dé àti ohun amáyédẹrùn fún aráàlú - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X
Aarẹ Bola Tinubu ti kepe awọn gomina ni Naijiria wi pe ki wọn pese iṣẹ, eto ilera alabọde atawọn ohun amayedẹrun mii fun araalu.
Tinubu ni oun naa ti n gbe awọn igbesẹ akin lori ọrọ aje eyi ti yoo jẹ ki araalu gbaye gbadun.
Aarẹ sọrọ yii nibi ipade ajọ NEC to n ri si eto ọrọ aje Naijiria ni ileeṣẹ ijọba niluu Abuja lanaa ọjọ kẹwaa oṣu Keji yii.
Tinubu ẹni ti Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ṣoju nibi apero naa sọ pe eto iṣelu nilo igboya, suuru ati aidawọ iṣẹ duro.
''Awọn igbesẹ ti a n gbe gbọdọ nipa to dara ninu aye awọn ọmọ Naijiria.
Iṣẹ gbọdọ wa fun araalu lati ṣe, ijọba gbọdọ ṣe ọna, kọ ile ẹkọ, bakan naa ni ijọba ni lati pese eto ilera to mọyan lori fawọn eeyan,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Aarẹ tun lo anfaani ipade ọhun lati ki Igbakeji Aarẹ Kashim Shettima fun bi o ṣe n dari ajọ NEC to n ri si eto ọrọ aje naa.
Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn gomina, minisita atawọn alabaṣiṣẹpọ pẹlu ajọ NEC fun ifọwọsowọpọ ati ipa tawọn naa n ko ninu eto ajọ naa.
Eto fifun araalu ni ireti ọtun kii ṣe ọrọ ẹnu lasan - Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ni ''eto fifun awọn araalu ni ireti tuntun kii ṣe ọrọ lasan, a ni lati ṣiṣẹ tọ ọ ki o le wa si imuṣẹ.
Mo nigbagbọ pe gbogbo awa ti a wa nibi ipade yii ni ọrọ wa ti ye ara wa lori eto fifun araalu ni ireti ọtun.
Ti a ba jọ ṣiṣẹ pọ ni a le fi ni eto ọrọ aje to dara ati orilẹede to gbọrọgẹjigẹ pẹlu.''
Aarẹ ni gbogbo eto tawọn gomina ba n ṣe gbọdọ jẹ ki awọn araalu jẹ anfaani kan tabi omiran.
Tinubu ni eto fifun awọn eeyan ni ireti ọtun ko gbọdọ jẹ ọrọ ẹnu lasan, bi ko ṣe pe kawọn eto naa pese iṣẹ atawọn nnkan amayedẹrun mii fun araalu.
Wo iye ti awọn gomina kọọkan gba lati apo ijọba apapọ lọdun 2025
Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ FAAC to n ṣagbatẹru pinpin owo fawọn ẹka ijọba ṣe ṣakọsilẹ rẹ, ipinlẹ Delta lo gbowo to pọju lọ lọdun 2025 pẹlu ₦649.67bn.
Ipinlẹ Rivers lo gbowo pọju ṣikeji lọdun 2025, ajọ FAAC ni ₦526.30bn ni ipinlẹ Rivers gba lati apo ijọba apapọ.
Ipinlẹ Eko lo ṣe ipo kẹta ninu awọn ipinlẹ to gba owo to pọ julọ lọdun 2025.
Ipinlẹ Eko ni ipinlẹ ti kii ṣe ipinlẹ to n gba ajẹmọnu owo ori epo lati ọdọ ijọba apapọ to ri owo to to ₦514.56 gba ni ọdun 2025.
Ipinlẹ Akwa Ibom to wa ni ipo kẹrin gba ₦494.23bn lati apo ijọba apapọ ni ọdun 2025.
₦488.08bn ni ipinlẹ Bayelsa gba lapo ijọba apapọ lọdun 2025, ipinlẹ naa lo si wa ni ipo karun un ninu awọn ipinlẹ to gbowo julọ.
Owo ti ko din ni ₦270.86bn ni ipinlẹ Kano to ṣe ipo kẹfa gba lati apo ijọba apapọ.
Ipo keje ni ipinlẹ Oyo wa ninu awọn ipinlẹ to gbowo julọ, ₦213.75bn ni ipinlẹ naa gba lati apo ijọba apapọ lọdun 2025.
Ipinlẹ Anambra gba ₦199.88bn lati inu apo ijọba apapọ lọdun 2025, ipinlẹ naa lo jẹ ipinlẹ kẹjọ to gba owo to pọ julọ lọdun 2025.
Ipinlẹ Borno gba owo ti ko din ni ₦198.75bn lati apo ijọba lọdun 2025.
Ipinlẹ Ondo lo wa ni ipo kẹwaa ninu awọn ipinlẹ to gbowo julọ lati apo ijọba apapọ lọdun 2025, ₦198.42 ni gbogbo owo ti ipinlẹ naa gba lọdun 2025.



























