Ilé ẹjọ́ nỉ Eko sọ ọmọ ilẹ̀ China méjì sẹ́wọ̀n fún jìbìtì orí ayélujára

Awon afurasi mejeeji gbe akọle EFCC lọwọ

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko, Daniel Osiagor ti ní káwọn ọmọ ilẹ̀ China méjì, tí wọ́n tún jẹ́ adarí iléeṣẹ́ Genting International Co. Limited, Huang Haoyu àti An Hongxu lọ máa fi aṣọ péńpé roko ọba lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta.

Ilé ẹjọ́ ní tàbí káwọn èèyàn náà san owó ìtanràn mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́ta náírà.

Ẹ̀sùn táwọn èèyàn náà jẹ́jọ́ lé lórí ni pé wọ́n ṣe èrú owó lórí ayélujára àti ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní kí wọ́n si ìlú fún ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wọ̀n wọn, tí wọ́n sì ní kí wọ́n dáwọn padà sí ìlú wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ẹ̀wọ̀n wọn.

Awọn eeyan naa lo wa lara awọn afurasi onijibiti iri ayelujara 792 ti ọwọ ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC nawọ gan ni ipinlẹ Eko, ni oṣu Kejila, ọdun 2024.

Nibi igbẹjọ to waye lọjọbọ ni awọn afurasi mejeeji naa ti sọ fun ile ẹjọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ sọ pe awọn ko jẹbi ki wọn to yii pada nibi igbẹjọ ọjọru.

Agbefọba to wọ awọn afurasi naa lọ si ile ẹjọ, Bilikisu Buhari-Bala rọ ile ẹjọ lati ṣe idajọ awọn ọkunrin naa nigba ti wọn ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

O sọ fun ile ẹjọ pe ẹwọn gbere ni ijiya ẹṣẹ akọkọ ati ikeji tawọn afurasi naa n koju, ti ijiya ẹṣẹ wọn kẹta si jẹ ẹwọn ọdun mẹrinla.

Buhari-Bala tun rọ ile ẹjọ lati gbe ẹsẹ le awọn dukia awọn ọmọ ilẹ China naa to wa ni agbegbe Oyin Jolayemi ati Bishop Oluwole ni Victoria Island, ipinlẹ Eko, ti wọn ṣawari lasiko ti iwadii n lọ lọwọ.

Lẹyin naa ni adajọ Osiagor dajọ pe ki Huang Haoyu ati An Hongxu lọ ṣẹwọn ọdun mẹrindinlaaadọta tabi ki wọn san owo itanran.

Ẹnikẹta wọn ti wọn jọ n jẹjọ, Audu Friday ni oun ko jẹbi ẹsun ti oun koju ti ile ẹjọ si ni awọn yoo tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ tirẹ.

Lara awọn ohun ti wọn ba lọwọ wọn ni ọpọlọpọ foonu, aga, tabili, kọmputa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Owo ti wọn ba ninu akoto owo ileeṣẹ, ti igbagbọ wa pe ọna eru ni wọn fi ko jọ le ni biliọnu mẹta naira.